Ìjọba fòfin de Tiktok lílò

Ìjọba fòfin de Tiktok lílò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ̀ èdè Senegal ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fòfin dé lílò Tiktok gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀ èdè kan ti ṣe ṣáájú.

Mínísítà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè Senegal, Moussa Bocar Thiam ní àwọn ti ṣe àwárí rẹ̀ pé Tiktok ní àwọn tó máa ń pín ọ̀rọ̀ òdì àtàwọn ọ̀rọ̀ tó le dá wàhálà sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà máa ń lò.

Thiam ní àwọn kò ní fi ààyè gba áàpù tó le da omi àláfíà ìlú náà rú.

Ṣáájú ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí ni ìjọba Senegal ti kọ́kọ́ dẹnu ayélujára orílẹ̀ èdè náà kọlẹ̀ tí mínísítà ọ̀hún sì ti ṣèkìlọ̀ fáwọn ènìyàn láti tẹ̀lé òfin ọ̀hún.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ṣì ń ní àǹfàní láti lo ayélujára wọn ṣùgbọ́n ojú òpó náà kò já gaara.

Àwọn ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ló ń ṣàmúlò ayélujára ní Senegal èyí tó jẹ́ ìdá méjìdínlọ́gọ́ta àwọn ènìyàn tó wà ní orílẹ̀ èdè náà.

Orílẹ̀ èdè Jordan náà ti fòfin de lílò Tiktok látàrí wáhàlá tó bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún lẹ́yìn tí àlékún bá owó epo bẹntiróòlù.

Láti ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 ni orílẹ̀ èdè náà ti gbégi dí lílo áàpù Tiktok láti ṣe àmójútó ìwọ́de tó lé ní ọ̀sẹ̀ kan tó wáyé ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún nítorí àlékún owó epo.

Adarí ètò ààbò Jordan sọ lórí Facebook pé ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn lórí ayélujára gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn ti ṣe àmúlò Tiktok lọ́nà tí kò tọ́.

Wọ́n ní àwọn kò ní fi ààyè gba gbígbé àwọn fídíò tó ń pè fún ìdàlúrú àti wàhálà láàyè ní orílẹ̀ èdè náà.

Ó ní ẹ̀ka náà ń ṣe àmójútó àwọn nǹkan tó ń jáde lórí ayélujára pàápàá lórí àwọn ìpèdè tó le dá wàhálà sílẹ̀.

Àwọn tó ń ṣàmúlò áàpù náà ní ìjọba Jordan kàn mọ̀-ọ́n-mọ̀ fẹ́ pa àwọn lẹ́nu mọ́ láti má pariwo wàhálà tó ń ló ní orílẹ̀ èdè náà síta.

Yàtọ̀ sí Jordan, àwọn orílẹ̀ èdè tó tún ti fòfin de lílo Tiktok ni Canada, Amẹ́ríkà, India, Taiwan, Pakistan, Afghanistan àti Iran.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here