Ìròyìn òfegè ni pé wọn ó forò lé àjòjì kúrò l’Ékò ó – Ìjọba

Ìròyìn òfegè ni pé wọn ó forò lé àjòjì kúrò l’Ékò ó – Ìjọba

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìròyìn òkèrè, bí ò bá lékan,a dínkan,ní báyìí, Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ní kí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀hún má tẹ́tí sí ìròyìn kan tó gba orí ayélujára kan pé orò fẹ́ jáde ní àwọn agbègbè kan.

Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn àdúgbò kan lọ́jọ́bọ̀, ogúnjọ́ àti ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Keje láàárín aago méjìlá sí aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí àwọn ọjọ́ náà.

Lára àwọn àdúgbò tí wọ́n ní orò náà ti máa wáyé ni Ikate,Ijora-Badiya, Amuwo-Odofin, Ojota, Ikorodu àti Somolu-Bariga àti agbègbè rẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n tún dárúkọ Igbobi-Sabe, Ojodu-Isheri, Isolo-Okota-Ilasamaja, Ejigbo-Idimu, Isheri-Ijegun, Ikotun-Igando, Iba, Lawanson-Itire àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ohun tí wọ́n kọ sórí ìròyìn náà ni pé kí àwọn obìnrin àti àwọn tí kìí bá ṣe ọmọ Eko ó fi ara pamọ́ láwọn àsìkò tí orò fi fẹ́ jáde náà pé ọmọ onílùú fẹ́ ṣe orò.

Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Gboyega Akosile nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní Alausa, Ikeja ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Akosile rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé kò sí nǹkan tó jọ pé orò kankan fẹ́ wáyé.

Ó ní kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá àti pé kìí ṣe ohun tó yẹ kí ìjọba tilẹ̀ máa dá sí ni.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here