Ẹ kéde mi bí ẹni jáwé olúborí ìbò Ààrẹ – Atiku sí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò

Ẹ kéde mi bí ẹni jáwé olúborí ìbò Ààrẹ – Atiku sí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, nínú ètò ìdìbò tó kọjá, Alhaji Atiku Abubakar ti rọ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò láti kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò náà.

Atiku Abubakar ní àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC gbà wí pé ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni òun ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Atiku sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ẹtì nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn èyí tí òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà láti fi tako ìjáwe olúborí Tinubu.

Nínú ọ̀rọ̀ náà èyí tí agbẹjọ́rò rẹ̀, Chris Uche ní INEC kò sọ wí pé àwọn ṣe àṣìṣe bí wọ́n ṣe ti ṣaájú sọ wí pé òun jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí.

INEC nínú èsì sí ẹjọ́ tí Atiku pè ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni Atiku tí jáwé olúborí.

Àwọn Ìpínlẹ̀ tí INEC kà kalẹ̀ pé Atiku tí jáwé olúborí ni Adamawa, Akkwa Ibom, Bauchi, Bayelsa, Borno, Delta, Ekiti, Gombe, Jigawa, Kaduna, Katsina, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Sokoto, Taraba, Yobe àti Zamfara.

Ó ní láti ìgbà náà títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí kò sí ìgbà tí INEC fi yí ọ̀rọ̀ náà padà.

Ó ní èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ẹni tó yẹ kí wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ nítorí náà kí Adájọ́ gbé ipò náà fún òun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here