Àwọn agbanipa dúró dè mí ní Yídì ọdún – Adeleke

Àwọn agbanipa dúró dè mí ní Yídì ọdún – Adeleke

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó jẹ́ ohun kàyééfì gbá à pé àwọn èèyàn kan tún lè má a lépa ẹ̀mí lásìkò tí olúkúlùkù n rawọ́ rasẹ̀ fún ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run Allah.
Kàyéèfì ibẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kan tó tẹnuGómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sẹnetọ Ademola Adélékè, jáde pé, ní àlàáfíà ni òun padà dé ilé lẹyìn rògbòdìyàn tó wáyé láàrin òun àti Sẹ́nétọ̀ tẹ́lẹ̀ tó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ajibola Bashiru níbi ádùrá ọdún.

Òwúrọ̀ Ọjọ́rú ni ìròyìn jáde pé Gómìnà Adélékè bínú kúrò ní ibi ádùrá ọdún lẹ́yìn tí àwọn jàǹdùkú tó jẹ́ ti SẹnetọSẹ́nétọ̀ Ajibola kọjú ìjà sí i.

Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ fún Gómìnà, Mallam Olawale Rasheed fi síta, ó ní ìyàlẹ́nu nlá ló jẹ́ fún Gómìnà lórí ipa tí Sẹ́nétọ̀ tẹ́lẹ̀ Ajibola kó nínú ìkọlù náà pẹ̀lú bó sẹ “jókòó sí ààyè ìjókòó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún Gómìnà níbi ádùrá ọdún náà.

“Gbogbo ìgbìyànjú láti mú kí Sẹ́nétọ̀ nígbà kan rí ọhún fi ààyè náà sílẹ̀ ló já sí pàbó.”

Mallam Olawale sọ pé lílù ni àwọn tọ́ọ̀gì Sẹ́nétọ̀ tẹ́lẹ̀ náà lu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú PDP tó bèèrè àpọ́nlé fún Gómìnà.

Ó ní gbogbo Eid ti dàrú nígbà tí Gómìnà fúnra rẹ̀ yóò fi dé síbi ètò ádùrá ọdún , tó sì yà á lẹ́nu púpọ̀ láti rí àwọn jàǹdùkú tó dì ìhámọ́ra káàkiri gbogbo ibùdó Eid.

“ Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò fi tó wa létí pé wọ́n kó àwọn jàǹdùkú náà wọlé sí Eid, pẹ̀lú èròńgbà láti pa Gómìnà àti àwọn èèyàn pàtàkì míràn tó wà nínú ìṣèjọba.”

Àtẹ̀jáde náà tún sọ pé ìgbà méjì ni Gómìnà gbìyànjú láti wọlé síbi ádùrá, àmọ́ tí àwọn jàǹdùkú ń yí i ká , èyí tó mú kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò rẹ̀ tètè gbé e kúrò wọ inú ọkọ̀ rẹ̀.

Gómìnà Adélékè tún wá rawọ́ ẹbẹ sí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun láti gba àlàáfíà láàyè lórí ìṣẹlẹ náà.

Bákan náà ló ní òun ti pàṣẹ fún àwọn ilé iṣẹ́ aláàbò, tó fi mọ́ kọmisanna ọlọ́pàá nipinlẹ Osun, láti fi òfin mú gbogbo àwọn tó lọwọ́ nínú ìkọlù sí Gómìnà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here