Kò dájú pé owó lítà epo bẹtiró kò tún ní lọ́ sókè sí– IPMAN

Kò dájú pé owó lítà epo bẹtiró kò tún ní lọ́ sókè sí– IPMAN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé ẹ̀jẹ̀ kò tíì tán lórí èékáná,torì pé iná n bẹ láṣọ ní bí àwọn ẹgbẹ́ àwọn alágbàtà eporọ̀bì, IPMAN ṣe sọ pé ó ṣeéṣe kí iye tí wọ́n ó má a ta lítà epo lọ sókè kọjá ẹgbẹ̀ta Náírà.

IPMAN sọ pé èyí lè wáyé nítorí kò sí àrídájú bóyá àwọn oníṣòwò epo yóó rí owó Dọla láti fi ra epo nílẹ̀ òkèèrè.

Àwọn onímọ̀ sọ pé ní kété tí àwọn alágbára epo bá fi bẹ̀rẹ̀ sí ní kó epo wọlé fúnra wọn láìpẹ, iye tí wọ́n ń ta lítà epo yóó wọ́n ṣí i jákèjádò Nàìjíríà.

Olórí ẹgbẹ́ IPMAN ní Àríwá Nàìjíríà, Bashir Dan-Mallam to fi ìdí ìròyìn yìí múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn, sọ pé ìjọba gbọdọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ tó yẹ láti dènà èyí.

Dan-Mallam sọ pé tí owó Dọla bá wà nílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu nìkan ló lè dènà kí owó lítà epo bẹtiró má lọ sókè sí i.

Àjọ elépo rọbì Nàìjíríà, NNPC, sọ pé ìdá ọgbọ̀n (30%) péré ni òun yóò máa a pèsè nínú epo ti orílẹ-èdè Nàìjíríà nílò, tí àwọn alágbàtà epo yóó sì má a pèsè èyí tó kù.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, N488 sí N550 ni àwọn iléepo ń ta lítà epo bẹtiró kan ní Nàìjíríà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here