Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí ọrọ ńlá kò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín tíì sinmi àròyé.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè South Africa, Cyril Ramaphosa ti rọ Ààrẹ Russia, Vladimir Putin láti fòpin sí ogun tó ń gbé ti Ukraine.

Ramaphosa pàrọwà yìí nígbà tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú Putin ní St Peterburg lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ààrẹ South Africa ọ̀hún àtàwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ adúláwọ̀ mẹ́fà mìíràn ni wọ́n ṣe àbẹ̀wò lọ sí Russia àti Ukraine láti lọ bẹ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti dáwọ́ ogun dúró.

Ṣáájú ni Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky sọ fún àwọn ikọ̀ náà lọ́jọ́ Ẹtì pé òun kò ní bá Putin jíròrò nígbà tó bá ṣì gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ àwọn.

Putin náà sọ fún àwọn adarí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà pé Ukraine kọ̀ láti jíròr]o pẹ̀lú òun.
Ramaphosa tún rọ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti tú àwọn ènìyàn wọn tí wọ́n fi sí àhámọ́ sílẹ̀ àti pé kí Russia dá àwọn ọmọdé tó kó lórí ilẹ̀ Ukraine padà sílé wọn.

Àmọ́ Putin fèsì padà pé Russia ń dá ààbò bo àwọn ọmọdé náà lọ́wọ́ ogun ni.

Ó ní àwọn kó àwọn ọmọ náà kúrò ní ibi tí pgun ti ń wáyé láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti ìlera wón ni.

Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ tọ ń rí sí ìwà ọ̀daràn ní àgbáyé ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ogun kan Russia lórí bó ṣe kó àwọn ọmọ náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹebí wọn.

Wọ́n ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Russia fi tipátipá kó àwọn ọmọdé ilẹ̀ Ukraine lọ sí Russia lọ́nà àìtọ́.

Ramaphosa tẹmpẹlẹmọ pe ipa tí ogun náà ń ní lórí àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò kéré rárá tó sì gbọdọ̀ wá sí òpin láìpẹ́.

Ó ní ogun ti ṣokùnfà ìdènà gbígbé oúnjẹ oní wóóró láti ilẹ̀ Ukraine àti ajílẹ̀ láti Russia wọ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ èyí tó ti ń fa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ.

“Ogun kò lè máa lọ títí láé, ó yẹ kí gbogbo igun wá ọ̀nà láti fòpin sí ogun yìí, a sì wá láti sọ fún-un yín pé ogun tó ń wáyé yìí kò tẹ́ wa lọ́rùn.

Àmọ́ Putin ní kìí ṣe ogun tó ń wáyé náà ló jẹ́ kí gbígbé àwọn oúnjẹ wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ dáwọ́ dúró àti pé òun kan sáárá sáwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà fún akitiyan wọn.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lọ síbi ìpẹ̀tù sááwọ̀ náà South Africa, Egypt, Senegal, Congo-Brazzaville, Comoros, Zambia àti Uganda.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here