Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ará ilé ẹni bá ń jẹ kòkòrò tí kò dáa, tí a kò bá sọ fún un, hẹ̀rẹ̀hùrù rẹ̀ kò ní-ín jẹ á fojú lóorun.
Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LASBCA), Gbolahan Oki ló fi ìkéde náà síta nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sínú ọjà náà lọ́jọ́ Ẹtì.

Oki ní láti ọdún 2016 ni àwọn ti ń ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ilé náà, tí àwọn sì ti ń ṣe àmì si wí pé àwọn máa wó wọn àti pé àbẹ̀wò òun náà wáyé láti sọ fún àwọn tó ń gbébẹ̀ láti kó kúrò lẹ́yẹ ò sọkà.

Èyí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa pòkìkí ọjà Alaba, níbi tí wọ́n ti máa ń ta ohun èlò ilé bíi ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, fírìjì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lórí ayélujára.

Àwọn ẹ̀yà Igbo ló pọ̀ tí wọ́n ń ta ọjà nínú Alaba tí àwọn kan sì ń sọ wí pé nítorí à ti gbẹ̀san ohun tó wáyé ní Eko lásìkò ìbò tó kọjá ló fa ìgbésẹ̀ ìjọba yìí.
Ẹ̀wẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oki ní láti ọdún 2016, 2020, 2022 títí di ọdún yìí ni àwọn ti ń fún àwọn ènìyàn tó ni àwọn ilé náà ni ìwé pé kí wọ́n kúrò níbẹ̀.

Ó ní àkíyèsí ọdún méje náà tó láti fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀ láti kúrò àmọ́ dípò kí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ìkìlọ̀ níṣe ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tí wan bá ti dé ibẹ̀.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ilé náà kò bá wà lára àwọn ilé 349 tí àwọn fi léde ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pé àwọn fẹ́ wó àmọ́ nítorí àwọn kìí ríbi ṣe iṣẹ́ àwọn tí àwọn bá dé ibẹ̀ nítorí ìkọlù tí wọ́n máa ń ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn kò jẹ́ kí àwọn le fi wọ́n sínú rẹ̀.

“Ohun tí à ń ṣe báyìí ni láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ “Task Force” Eko láti lè ri wí pé á ri àwọn ilé náà wó palẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.

“Ó pọn dandan fún wa láti wó àwọn ilé náà báyìí nítorí wọ́n ti di ẹgẹrẹ mìtì, tí wọ́n sì lè ṣe àkóbá fún àwọn ilé mìíràn tó wà ní agbègbè wọn àti àwọn tó ń ta ọjà níbẹ̀ pàápàá.”

Ó fi kun pé ìjọba yóò tẹ̀síwájú láti máa pàtàkì ẹ̀mí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láì fi ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe, kí ìgbé ayé le rọrùn fún mùtúmùwà.

 

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta ọjà nínú Alaba International Market, Theo Ezeani sọ fún akọ̀ròyìn pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ń gbọ́ pé ìjọba fẹ́ wó àwọn ilé kan nínú ọjà náà.

Ezeani ní àwọn kò rí ìwé ìkìlọ̀ kankan láti ọdún 2016 èyí tí ìjọba ní àwọn fi ṣọwọ́.

Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ kò mọ̀ nípa ìwé tí ìjoba ní àwọn ti ń kó ránṣẹ́ tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun nítorí ó ti pẹ́ tí òun ti wà nínú ọjà náà.

“Kò sí pigbà kankan tí a sọ ohun tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìpàdé wa, àwọn tí a gba ipò lọ́wọ́ wọn náà kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ fún wa, lórí amòhúnmáwòrán ni mo ti kọ́kọ́ rí ìròyìn náà lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì. ”

Ezeani ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn tó ni ilé gangan ni ìjọba kọ̀wé ránṣẹ́ sí àmọ́ àwọn tí àwọn ń ta ọjà níbẹ̀ kò gbọ́ nǹkankan.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́jà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ẹrù wọn kúrò níbẹ̀ nítorí ohun tí àwọn gbọ́ ni pé ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndílógún, oṣù Kẹfà ni ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwó àwọn ilé náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here