Àwọn alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní olè kò ní-ín jà gbà, kó má ṣe é lójú fìrí,
amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbà fún Gómìnà Akeredolu lórí ọrọ̀ àkànṣe iṣẹ́, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ti bu ẹnu àtẹ lu àwọn olóṣèlú kan tó ní wọ́n ń ṣe ìpàdé bonkẹlẹ kiri láti fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lólè
Ọmọwe Ọdẹbọwale nínú atẹjade kan èyí tó fi síta ṣàlàyé pé àwọn olóṣèlú kan ní ìpínlẹ̀ Ondo ń lo àìsíńlé ologini Gómìnà Akeredolu láti fi sọ araa wọn di èkúté ilé tó fẹ́ ti ẹnu bọ aṣuwọn ìpínlẹ̀ náà,
Ó ní ọgbọn tí àwọn olóṣèlú ọhún ń dá ni láti dá iná èdè àìyédè sílẹ̀ láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan lọnà àti leè fi gba àkóso agbára ní ìpínlẹ̀ náà.