Kín ló dé! Ìdílé àwọn òṣèrè yìí pàpà dàrú
Ọrẹ Òtítọ́jù
Sùúrù kìípọ̀jù, à fi bí kó bá
ní-ín tó lókù .Ayé ò ní-ín yé sọ̀rọ́ ọ wa.
Lóòtótọ́ ló ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti ń gbé e pooyi ẹnu pé kò jọ pé aàọṣepọ̀ tó dán mọ́rán wà láàrin àwọn òṣèré ilẹ̀ wa méjì tí wọ́n jẹ́ tọkọ-tìyàwó, Bukọla Awoyẹmi tí gbogbo èèyàn mọ sí Arugba àti Damọla Ọlatunji, tóun náà jẹ́ òṣèré.
Ibi tára ti ń fu àwọn èẹyàn ìṣesí wọn lásìkò ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bí wọn, àti pé àwọn olólùfẹ́ wọn kò sì tún rí wọn papọ̀ bí wọ́n ṣe jọ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ni ko ka eleyii si, bẹẹ ni awọn oṣere mejeeji yii naa ko sọrọ jade lati sọ pe bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ lori pe igbeyawo wọn ti tu ka, ti onikaluku si ti n lọ lọtọọtọ.
Ṣugbọn gbogbo awuyewuye yii ti wa sopin bayii pẹlu bi Bukọla Arugba ṣe gbe iwe ipinya laarin oun ati Damọla ti lọọya rẹ kọ sori ikanni Sítágíràmù rẹ lati sọ fun gbogbo eeyan pe oun ko si pẹlu baba ọmọ oun naa mọ, ati pe awọn mejeeji ti pin gaari.
Ninu lẹta naa ti agbẹjọro rẹ kọ ọhun lo ka bayii pe, ‘‘Awa gẹgẹ bii agbẹjọro Arabinrin Bukọla Awoyẹmi ti gbogbo eeyan mọ si Arugba n fi asiko yii sọ fun yin pẹlu aṣẹ ti a gba lati ọdọ onibaara wa ka too gbe ọrọ yii jade pe a n fi asiko yii kede pe a fẹ ki ẹ fi eleyii sọkan pe onibaara wa, Bukọla Awoyẹmi, ati Damọla Ọlatunji ko ni ajọṣepọ kankan papọ mọ. Onikaluku ti n lọ nilọ rẹ, lai ni ikunsinu kankan sira wọn. Ko sigba kankan ti awọn mejeeji ṣegbeyawo, ṣugbọn Ọlọrun fi ibeji ta wọn lọrẹ.
‘‘Awọn mejeeji ni wọn ti jọ fohun ṣọkan pe awọn yoo ma ri si itọju awọn ọmọ mejeeji yii’’.
Ohun ti awọn kan n gbé pooyi ẹnu ṣugbọn ti ẹri rẹ o mulẹ ni pe oṣere-kunrin naa ti fun ẹlomi-in loyun nita.
Bẹ́ ò bá gbàgbé, kí Damọla tóó fẹ́ Arugba ló ti kọ́kọ́ ṣegbeyawo pẹ̀lú ọmọbìnrin kan, Raliat Abiọdun Ṣobọwale, lọjọ kẹtala, oṣù Kẹrin, ọdún 2013.
Ìgbéyàwó náà kò ju ọdún kan lọ tó fi túká. Ẹ̀sùn àgbèrè ni ọmọbìnrin náà fi kan Damọla. Bukọla Awoyẹmi tí Damọla padà fi fi sílẹ̀, ti wọ́n sì ti kọ ara wọn báyìí ,ni ọmọbìnrin tó ń gbé nílùú òyìnbó nígbà náà fẹ̀sùn kàn pé ó ń ṣe wọlé-wọ̀de pẹ̀lú ọkọ òun, èyí tó sì padà fa ìpínyà láàrin wọn.