Seyi Makinde yọ Auxiliary alága onímọ́tò n’Ibadan

Seyi Makinde yọ Auxiliary alága onímọ́tò n’Ibadan

Ọrẹ Òtítọ́jù

Lẹ́yìn ìbúrawọlé fún sáà ìkejì ìjọba Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣeyi Makinde lọ́jọ́ Ajé ni ìròyìn mìíràn tún jáde wí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gba iṣẹ́ lọwọ́ alamojuto ìgbòkègbodò ọkọ, ‘Park Management System (PMS)’, Alhaji Mukaila Lamide tí ọpọ èèyàn mọ sí “Auxiliary” àti gbogbo ìgbìmọ̀ rẹ̀.

Nínú atẹjade ti olori oṣiṣe tuntun n’ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Segun Ogunwuyi fi lede lorukọ Gomina, o ni, “Mo ti gba aṣẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lati fi ọrọ too yin leti nipa ituka igbimọ to n ṣe amojuto igbokegbodo ọkọ bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023”.
Gbogbo wa la mọ wi pe ọrọ kii dede ṣẹlẹ bi ko ba ni idi. Awọn igun kan ninu ẹgbẹ awakọ meji ọtọọtọ to n ṣe akoso igbokegbodo ọkọ tẹlẹri n’ipinlẹ Ọyọ, ‘National Union of Road Transport Workers(NURTW)’, ati ‘Road Transport Employers Association of Nigeria (RTEAN)’ ni a gbọ pe wọn ṣe abẹwo sí Ṣeyi Makinde saaju eto idibo ti o gbe Gomina naa wọle fun saa ikeji, wọn si ṣe ileri fun un wi pe awọn yoo baa ṣiṣẹ pọ ki o le de ibi ilepa rẹ.

Bo tilẹ jẹ wi pe ifanfa wa laarin ẹgbẹ mejeeji ati Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Makinde gba lati fun wọn ni aye ki aigbọraẹni ye ti wọn ni tẹlẹri le di ohun igbagbe.

Eyii lo mu ki Gomina ke si alakoso igbimọ to n ṣe akoso awọn ọlọkọ ero n’ipinlẹ Ọyọ, PMS, iyẹn Alaaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si ‘Auxiliary’ wi pe ki o fi aye gba awọn igun ẹgbẹ awakọ ero mejeeji naa lẹyin ti wọn gba lati dara pọ mọ gomina ki alaafia si le tubọ jọba lẹka awọn ọlọkọ ero ni ipinlẹ Ọyọ.
Ṣe wọn ni Oriṣa jẹ n pe meji obinrin ko denu. Igbesẹ yii ko dun mọ Auxiliary ninu, idi si niyi ti o fi kọ eti ọgbọin si aṣẹ ti Makinde pa.

Gbogbo akitiyan lati rii pe iṣọkan jọba laarin ẹgbẹ awọn awakọ ero lo n ja si pabo pẹlu bi Auxillary ṣe faake kọri pe oun ko ni ba awọn ẹgbẹ awakọ ero meji toku, iyẹn NURTW ati RTEAN ṣe

Ohun ti a gbọ siwaju sii ni pe Gomina Seyi Makinde n fi ara daa gbogbo iwa aigbọran ati ti inu mi ni n o ṣe yii pelu erongba wi pe yoo pada fi aye gba wọn, eleyi ti wọn ba wọeto burawọle fun Makinde lati ṣe ijọba fun saa ikeji.
Lẹyin gbogbo pọpọsinsin ayẹyẹ iburawọle fun saa keji gomina Seyi Makinde ni papa iṣire Ọbafẹmi Awolọwọ, ti ọpọ ṣi mọ si Liberty Stadium nilu Ibadan lọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023 ni awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ ero mejeeji, iyẹn NURTW ati RTEAN ba ni ki awọn sin Gomina de ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ikọlaba lati kii ku oriire. Ni Ibẹ ni a gbọ wi pe Auxiliary ati awọn eeyan rẹ ti pade wọn ti ọrọ si di iṣu ata yan-an-yan-an.

Ọrọ yii lo bi Gomina Ṣeyi Makinde ninu ti o si pa aṣẹ wi pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ Auxiliary ati awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ rẹ.

Lati igba ti ijọba si ti ṣe ikede yii ni ariwo ti n sọ lọtun losi lori iwa ipa ti awọn janduku kan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ ara ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to wa labẹ Auxiliary n hu lawọn agbegbe bii Olodo, Iwo Road ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni gbogbo awọn adugbo yii ni awọn eeyan ti n ke gbajare wi pe awọn n gbọ iro ibọn lakọ-lakọ.

Nínú oṣù karún- ún ọdún 2019 ni Makinde fi òfin de ẹgbẹ́ awakọ̀ NURTW àti RTEAN nítorí wàhálà tí wọ́n fa lórí ipò adarí, lẹ́yìn èyí sì ni ó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ PMS tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ eléyìí tí Auxiliary àti ìgbìmọ̀ rẹ̀ ń ṣe àkóso fún.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here