Adedoyin gbọ́jọ́ ikú ó pohùnréré níwájú adájọ́ Fẹ́mi Akínṣọlá Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí Ọlọ́run bá rí ọ, jẹ́ kí èèyàn náà ó rí ọ gbẹ̀rí jẹ́.Ọ̀tafà sókè yíbó bóri, b’ọ́ba ayé ò rí ọ, dájúṣáká, t’Ọ̀run n wò ọ́.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà ní akọ igi kò gbọdọ̀ soje, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí lọ́dọ̀ Dókítà Rahaman Adedoyin, ìyẹn lẹ́yìn tí Onídàájọ́ Adepele Ojo ka ìdájọ́ rẹ̀ tán, tó ní òun pàṣẹ kí wọ́n lọ̀ọ́ yẹgi fún ọkùnrin tó ni ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Odùduwà yìí títí tí ẹ̀mí yóó fi bọ́ lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó máa gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ ti kò ní í bara jẹ́. Níṣe ni ojú ọkùnrin yìí yípadà, béèyàn bá sì wo ìrísí rẹ̀ nílé-ẹjọ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun yìí,oní tọ̀hún yóó mọ́ pé òógùn tó ń jáde lára ọkùnrin náà gbóná janjan bíi omi gbígbóná ni. Bí adájọ ti parí mrọ̀ rẹ̀ ni Adedoyin nawọ́ sókè, ó lóun ní ohun tí òun fẹ́ sọ. Ṣùgbọ́n Adájọ́ Ojo ṣẹ́wọ́ sí lọ́ọ́yà Adedoyin, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí lọkùnrin náà fẹ́ sọ. N ni agbẹjọ́rò rẹ̀ bá ní kí adájọ jọ̀wọ́ jàre, gba oníbàárà òun láàyè láti sọ̀rọ̀, nígbà tí wọ́n gbé gbohùngbohùn sí í lẹ́nu. Tàánútàánú lọkùnrin náà fi sọ pé, ‘Ọlọ́run rí mi o, Ó mọ pé mi ò pààyàn, mi ò sì rán ẹnikẹ́ni láti pààyàn… Ọ̀rọ̀ yìí ló ń sọ lọ́wọ́ tí Adájọ́ àgbà fi dá a mọ́ ọn lẹ́nu, ló bá ní , ‘òní kì í ṣe ọjọ́ ọ̀rọ̀ o, ó ní ọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ nìyẹn, kò sì lè tẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí ìdájọ ti wáyé, wọ́n ní tó bá dé ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn, kó máa lọ̀ ọ́ sọ gbogbo ohun tó bá ní lọkàn tó fẹ́ ẹ́ sọ. Èyí tó ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láàánú nínú ọ̀rọ̀ náà ni ti ọ̀kan nínú àwọn ọmọọṣẹ́ Adedoyin tí wọ́n jọ dájọ́ ikú fún . Níṣe ni ọmọkùnrin náà wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọ̀gá rẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkorò.

Adedoyin gbọ́jọ́ ikú ó pohùnréré níwájú adájọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí Ọlọ́run bá rí ọ, jẹ́ kí èèyàn náà ó rí ọ gbẹ̀rí jẹ́.Ọ̀tafà sókè yíbó bóri, b’ọ́ba ayé ò rí ọ, dájúṣáká, t’Ọ̀run n wò ọ́.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà ní akọ igi kò gbọdọ̀ soje, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí lọ́dọ̀ Dókítà Rahaman Adedoyin, ìyẹn lẹ́yìn tí Onídàájọ́ Adepele Ojo ka ìdájọ́ rẹ̀ tán, tó ní òun pàṣẹ kí wọ́n lọ̀ọ́ yẹgi fún ọkùnrin tó ni ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Odùduwà yìí títí tí ẹ̀mí yóó fi bọ́ lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó máa gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ ti kò ní í bara jẹ́. Níṣe ni ojú ọkùnrin yìí yípadà, béèyàn bá sì wo ìrísí rẹ̀ nílé-ẹjọ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun yìí,oní tọ̀hún yóó mọ́ pé òógùn tó ń jáde lára ọkùnrin náà gbóná janjan bíi omi gbígbóná ni.

Bí adájọ ti parí mrọ̀ rẹ̀ ni Adedoyin nawọ́ sókè, ó lóun ní ohun tí òun fẹ́ sọ. Ṣùgbọ́n Adájọ́ Ojo ṣẹ́wọ́ sí lọ́ọ́yà Adedoyin, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí lọkùnrin náà fẹ́ sọ. N ni agbẹjọ́rò rẹ̀ bá ní kí adájọ jọ̀wọ́ jàre, gba oníbàárà òun láàyè láti sọ̀rọ̀, nígbà tí wọ́n gbé gbohùngbohùn sí í lẹ́nu. Tàánútàánú lọkùnrin náà fi sọ pé, ‘Ọlọ́run rí mi o, Ó mọ pé mi ò pààyàn, mi ò sì rán ẹnikẹ́ni láti pààyàn… Ọ̀rọ̀ yìí ló ń sọ lọ́wọ́ tí Adájọ́ àgbà fi dá a mọ́ ọn lẹ́nu, ló bá ní , ‘òní kì í ṣe ọjọ́ ọ̀rọ̀ o, ó ní ọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ nìyẹn, kò sì lè tẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí ìdájọ ti wáyé, wọ́n ní tó bá dé ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn, kó máa lọ̀ ọ́ sọ gbogbo ohun tó bá ní lọkàn tó fẹ́ ẹ́ sọ.

Èyí tó ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láàánú nínú ọ̀rọ̀ náà ni ti ọ̀kan nínú àwọn ọmọọṣẹ́ Adedoyin tí wọ́n jọ dájọ́ ikú fún . Níṣe ni ọmọkùnrin náà wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọ̀gá rẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkorò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here