Dúkìá mi dínkù sí iye mo kó wọ ìṣèjọba lọ́dún 2019 – Makinde

Dúkìá mi dínkù sí iye mo kó wọ ìṣèjọba lọ́dún 2019 – Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ni pé,ẹni bá róoreọ̀fẹ́ àti gbá èèkù isàkóso ìjọba mú níbikíbi ní Nàìjíríà, onítọ̀ún lọ buta ni, àbùkún ọrọ̀ yọ̀tọ̀mí ló wà. Àmọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde, ti sọ pé iye dúkìá tí òun ní ti dínkù sí ju ti ìgbà tí òun kọ́kọ́ gorí àléfà lọ.

Makinde ló sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún lásìkò tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó kéde iye dúkìá tó ní ní ọọ́fíìsì àjọ tó n yẹ iye dúkìá tí àwọn olóṣèlú ní wò, CCB, nílùú Ìbàdàn.

Tí ẹ kò bá gbàgbé, lọ́dún 2019 ni Makinde kọ́kọ́ kéde Iye dúkìá tó ní kó tó bẹ̀rẹ̀ sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà, tí iye gbogbo ohun tó ní sì lé díẹ̀ ní bílíọ̀nù méjìdínláàdọ́ta.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe dandan ni kí olóṣèlú kéde iye dúkìá tó ní, àmọ́ ó tọ̀nà kí wọn ṣe bẹ́ẹ̀ .

Ó ní “Gẹgẹ bíi alakalẹ òfin, ó yẹ kí èèyàn kéde iye dúkìá tó ní kó tó gorí àléfà àti lẹ́yìn sáà rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí sáà wà àkọ́kọ́ ti n lọ sópin, mo gbọ́dọ̀ kéde iye dúkìá mi kí á to tún bẹ̀rẹ̀ sáà míì.”

“Ìdí rèé tí mo fi wá síbí láti kéde iye dúkìá tí mo ní kí á tó bẹ̀rẹ̀ sáà kejì.”

“Mo mọ pé gbogbo yín ni ẹ mọ iye dúkìá tí mo ní kí á tó bẹrẹ sáà akọkọ, amọ mo fẹ́ sọ fún yín pé láàrin ọdún meẹ́rin, dúkìá mi ti dínkù ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nítorí mi ò rí ààyè láti bójú tó àwọn okòwò mi.”

“Ọrọ bí ipinlẹ Oyo yóó ṣe dára ni a gbájúmọ́, nítorí náà kò yàmí lẹ́nu bí nǹkan ṣe rí àmọ́ kò séwu.”

Tí ẹ kò bá gbàgbé, ọdún 2019 ni agbẹnusọ Makinde, Taiwo Adisa kéde gbogbo dúkìá Gómìnà ọhun tí iye rẹ̀ sì jẹ́ ₦‎48b.

₦‎48b náà jẹ àpapọ̀ owó tó ní lọ́wọ́, ní bánkì, tó fi mọ́ àwọn Ilé lóríṣiríṣi àtàwọn ohun tó wà nínú ilé náà.

Lára awọn dúkìá náà tún ni awọn ohun ìdókoòwò onírúurú láwọn ilé ìfowópamọ́ tó jẹ́ ti Gómìnà ọ̀hún, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn èyí tó jẹ ti àwọn iléeṣẹ́ rẹ̀.

Lára àwọn ileeṣẹ tó jẹ ti Makinde tí Adisa kéde ní Makon Engineering and Technical Services Limited; Energy Traders and Technical Services Limited; ati Makon Oil and Gas Limited.

Òun náà ló tún ni Makon Group Limited, Makon Construction Limited àti Makon Power System Limited

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here