Ẹ fọkànsí àyípadà rere Nàìjíríà níjọba yìí– Ààrẹ Bola Tinubu

Ẹ fọkànsí àyípadà rere Nàìjíríà níjọba yìí– Ààrẹ Bola Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àlà ni, àlá kọ́, ní báyìí n tó jọ àlá lójú àwọn èèyàn Orílẹ̀ yìí kan ti já sí òòtọ́ báyìí níbi tí Bọla Tinubu Ààrẹ orílẹ-èdè Nàìjíríà ti ń sọ̀rọ̀ àkọ́sọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ wọn. Ó ní ìṣèjọba òun yóò jẹ́ aṣojú ọmọ Nàìjíríà ní ìgbà gbogbo àti pé àwọn yóò máa gba ìmọràn káàkiri lórí ìgbésẹ̀ gbogbo tí àwọn bá fẹ́ gbé.

Ó ní òun kò ní fí ọnà kọnà yan àwọn tó bá òun díje du ipò Ààrẹ ní pọṣìn nítorí pé ẹ̀tọ́ kan náà ni àwọn jùmọ ní, ìfẹ́ orílẹ-èdè Nàìjíríà kan náà làwọn jọ ń jà fún. Ó fi kún un pé ẹtọ wọn ni ìgbésẹ̀ àti tọ ilé ẹjọ́ lọ tí wọ́n gbé, òun sì fara mọ́ ọ.

Tinubu ní ìṣèjọba òun yóó mú ìdàgbàsókè tó yẹ bá ìhùwàsí àti ìgbáyégbádùn gbogbo ọmọ Nàìjíríà nípa mímójútó ọrọ̀ ajé, àparò kan kò ga jùkan lọ.

Ó ní láì pẹ àwọn ìlànà ètò ọrọ̀ ajé tí ìjọba òun fẹ́ gúnlé yóò bẹrẹ sí ní jáde síta fáráàlú láti rí.

Ààrẹ Tinubu ní ìṣèjọba òun yóò máa bọwọ fún òfin ní ìgbà gbogbo, yóó sì dáàbò bo Nàìjíríà lọwọ́ ìkọlù gbogbo.

Bákan náà ló ní ọwọ́ yóó kan ètò ọrọ̀ ajé pẹ̀lú ìdánilójú láti mú ìdàgbàsókè bá ìpèsè iṣẹ́ àti dídópin ìṣẹ́ àti ìyà.

Ó ní àwọn obìnrin àtàwọn ọ̀dọ́ yóó kópa tó jọju nínú ìṣèjọba tuntun yìí.

Ààrẹ Tinubu ní iṣẹ́ kíákíá yóó wáyé lórí ètò ààbò nítorí kò sí bí ètò ọrọ̀ Ajé àti ìbọ̀wọ̀ fún òfin ṣe leè fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ láàrin ààbò tó mẹ́hẹ.

Ó ní àtúntò ìlànà àti ètò ààbò pẹlú ìpèsè kóríyá fún àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò yóó mókè.

Ó ní ìṣèjọba òun yóò tún mójútó ọ̀rọ̀ ìdáléeṣẹ́ sílẹ̀, èyí tó ní yóó le mú kí iye ọjà tí a ń kó lọ tà lókè òkun pọ ju iye ti wọn n ko wa ta lórílẹ́èdè Naijiria.

Lórí ọ̀rọ̀ ìpèsè iná, ó ní ètò yóó kalẹ̀ fún ìpèsè iná ó ní òun yóó ṣe ètò ìpèsè iná fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé aráàlú àti pé òun yóò ṣe kóríyá fún àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ láti ṣe ìdásílẹ̀ ileeṣẹ amunawa aladani tiwọn.

Bákan náà ló fi dá àwọn ilé-iṣẹ́ àti oludokoowo lójú pé ìṣèjọba òun yóó ṣe àgbéyẹ̀wò gbogbo ẹsùn sísan owó orí lọ́nà púpọ àti gbogbo àwọn nǹkan ìpèníjà míràn tó ń kojú ìdókoòwò sílẹ̀.

Ó ní ìlérí òun láti pèsè iṣẹ́ mílíọ̀nù kan nípasẹ̀ ẹ̀ka ìmọ ẹ̀rọ ṣì dúró digbí.

Lórí ètò ọ̀gbìn, Ààrẹ Tinubu ní àwọn àwùjọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbín yóò wà káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti leè mú kí iye ọ̀gbín tó ń jáde lórílẹ̀ èdè yìí túbọ̀ yanrantí kí oúnjẹ lè pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu fáráàlú.

Ó ní òun yóò tún tẹsiwaju pẹ̀lú iṣẹ́ ribiribi tí ìjọba Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari gbé ṣe lẹ́ka ìpèsè ohun èlò amáyédẹrùn.

Lórí ọ̀rọ̀ owó ìrànwọ́ orí epo, Ààrẹ tuntun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣàlàyé pé inú òun dùn pé wọ́n ti yọ sísan owó ìrànwọ́ epo, “subsidy” nínú ìṣúná ọdún yìí èyí tó fihàn pé owó ìrànwọ́ orí epo ti ròkun ìgbàgbé.

Lórí ọrọ̀ pàṣípààrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè, Ààrẹ Tinubu sọ pé kò ní sí ọjà pàṣípààrọ̀ olójúméjì mọ́ nítorí pé bánkì àpapọ̀ lábẹ́ ìṣèjọba òun yóó wọ́gile.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here