Èèyàn méje tó sọ̀kò gbẹ̀mí Ọlọ́pàá dèrò àtìmọ́lé n’Ìbàdàn

Èèyàn méje tó sọ̀kò gbẹ̀mí Ọlọ́pàá dèrò àtìmọ́lé n’Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìpátá kìí bímọ re, bí ò bá bí ikú a sì bí ẹ̀wọ̀n gbére.
Àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé wọ́n lu ọlọ́pàá kan, Rìpẹ́tọ̀ Augustine Okoro títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀ ní ibùdó ọlọ́pàá tó n bẹ ní pópónà Iṣẹyin, íi agbègbè Mọniya nílùú Ìbàdàn ti fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Àwọn afurasí náà ni: Sarafa Lateef (ẹni ọgbọ̀n ọdún), Saminu Ibrahim (ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n), Oloso Sikiru (ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì), Fatai Yusuf (ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta), Moruf Olanrewaju (ẹni ọdún méjìlélógójì), Isiaka Rafiu (ẹni ogójì ọdún), àti Anuoluwa Akinola (ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n).

Agbèfọ́ba, ASP Amos Adewale sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà gbìmọ̀pọ̀ lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ní òpópónà Ìṣẹ́yìn ní agbègbè Mọniya Ìlú Ìbàdàn, tí wọ́n sì ṣe ikú pa Rìpẹ́tọ̀ Augustine Okoro, ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì.

Adewale fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà lu Okoro, wọ́n sì sọ òkò paá lẹ́nu iṣẹ́ ní agbègbè náà.

Ó ní ìtàpásófin yìí tako òfin ìwà ọ̀daràn ti ọdún 2000 n’ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ Májísírètì, E. A. Idowu ti ilé ẹjọ́ Májísírètì Iyaganku tí ó kọ láti tẹ́wọ́gba ẹ̀bẹ̀ àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà ló pa àṣẹ pé kí wọ́n sọ wọ́n sí àtìmọ́lẹ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi.

Adájọ́ náà tọ́ka ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn fún àmọ̀ràn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here