Nnamdi Kanu kò lè kú sí àtìmọ́lé – Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ sọ̀rọ̀

Nnamdi Kanu kò lè kú sí àtìmọ́lé – Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ sọ̀rọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti sún ìgbẹ́jọ́ adarí ikọ̀ IPOB, Nnamdi Kanu síwájú.

Ilé ẹjọ́ kéde ìsúnsíwájú yìí lẹ́yìn tí agbẹjọ́rò ìjọba A. Gazali tako ìgbẹ́jọ́ ẹsùn méjì tó wà níwájú wọn, èkíní ni láti gba beeli rẹ̀, èkejì sì ni láti gbé e kúrò ní àhámọ́ DSS lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abùjá nítorípé kò tíì fi ìdáhùn rẹ̀ ránṣẹ.

Agbẹjọ́rọ̀ ìjọba, A. Gazali rọ ilé ẹjọ́ láti fún un di ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá Oṣù Kàrún, ọdún 2023.

Agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu náà, Mike Ozekhome sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun ti ṣetán fún ilé ẹjọ́ fún ìgbẹ́jọ́ náà tó sì sọ fún adájọ pé kí wọ́n fún wọn ní déètì tó súnmọ́ jù nítorípé ipò tí Nnamdi Kanu wà ní àhámọ́ àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS kò dára rárá.

“Olúwa mi, Nnamdi Kanu ń ṣàìsàn wọ́n sì ti buwọ́lu ìwé tó yẹ kó lọ fi ṣe iṣẹ́ abẹ ṣùgbọ́n àwọn àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kò jẹ́ kó jáde.

À n bẹ̀bẹ̀ kí wọ́n jẹ́ ká gbé e kúrò ní àhámọ́ DSS lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje kó lè baà rí ìwòsàn gbà bíi àwọn tó kù, ẹ̀rù sì n bà mí kó má kú sọ́wọ́ àwọn DSS nítorípé wọn ò ṣáà kìí dá ẹjọ́ fún òkú”. Ozekhome tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún sọ èyí bó ṣe ń bẹ ilé ẹjọ́.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here