Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun pààyàn mẹ́ta, wọ́n gbé òkú wọn sá lọ l’Ọ́wọ́

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun pààyàn mẹ́ta, wọ́n gbé òkú wọn sá lọ l’Ọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn mẹ́ta ni wọ́n pàdé ikú òjìji nílùú Ọwọ, tí í ṣe ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ Ọwọ, lọjọ Ìṣẹgun, ọjọ́ kẹsan-an, oṣù Karùn-ún, ọdún 2023 yìí.

Ohun tí ìròyìn Òwúrọ̀ gbọ ni pé wọ́n yìnbọn pa àwọn èèyàn ọhún nínú ikọlu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó wáyé nílùú náà lalẹ ọjọ́ ìṣẹlẹ yìí.

Níbi tó le dé, wọ́n sì ń wá òkú àwọn tí wọ́n pa yìí, tí wọn kò sì tí ì mọ ibi tí wọ́n wà ní gbogbo àsìkò tá a fi ń kọ ìròyìn yìí lọwọ́. Wọ́n ní àwọn jàǹdùkú ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà kọ láti fi òkú wọn sílẹ̀, nítorí lẹ́yìn tí wọ́n yinbọn pa wọ́n tán ni wọ́n tún wọ́ òkú wọn lọ síbi tí ẹnikẹ́ni kò tí ì mọ̀.

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún múlẹ̀ fáwọn oníròyìn, Olùbádámọ̀ràn fún Gómìnà lórí ètò ààbò, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, ní àwọn Àmọ̀tẹ́kùn àtàwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò mí-ìn ti wà níkàlẹ̀ láti bojuto ètò ààbò nílùú Ọ̀wọ̀.

Adelẹyẹ tó jẹ́ ọ̀gá Amọtẹkun, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Òǹdó, ní ìgbésẹ ti ń lọ lábẹ́nú láti rí àwọn oníṣẹ́ẹbi náà mú níbi yòówù kí wọ́n lè fara pamọ́ sí.

Alukoro Iléesẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó, Abilékọ Funmilayọ Ọdunlami, ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá tó ń gbógun ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìpínlẹ̀ Òǹdó ti lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún láti pèṣè ààbò fáwọn aráàlú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here