Dókítà àgbà n najú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n torí ó bá aláìsàn lòpọ̀

Dókítà àgbà n najú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n torí ó bá aláìsàn lòpọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan tó wà ní ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara ti pàṣẹ pé kí dókítà àgbà ilé ìwòsàn Ayodele Hospital ní ìlú Ilorin, Dókítà Ayodele Joseph lọ máa gba afẹ́fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ìgbà kan ná.

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá oṣù Karùn-ún, ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ náà ní kí dókítà ọ̀hún tó jẹ́ adarí ilé ìwòsàn náà wà ní àhámọ́ ná lórí ẹ̀sùn wí pé ó fi tipátipá bá ọ̀kan lára àwọn aláìsàn tó wà ní ilé ìwòsàn rẹ̀ lòpọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ ìwádìí àwọn ọlọ́pàá ṣe sọ, dókítà Ayodele fipá bá aláìsàn náà, tí òun náà jẹ́ nọ́ọ̀sì fúnra rẹ̀, sùn nígbà tó lọ sí ilé ìwòsàn náà fún ìtọ́jú.
Ìwádìí ọlọ́pàá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé afurasí náà fún aláìsàn ọ̀hún oògùn oorun lò kó tó di wí pé ó ba ní àjọṣepọ̀ láì gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

Wọ́n ní àwọn ṣe àwárí fídíò kan tó ṣàfihàn bí dókítà náà ṣe ń fipá bá obìnrin náà lòpọ̀ àti pé ìwádìí àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fipá bá obìnrin náà lòpọ̀.

Olùpejọ́, Gbenga Ayeni sọ fún ilé ẹjọ́ bí ìwà tí dókítà náà hù ṣe lágbára tó, tó sì rọ ilé ẹjọ́ láti fi dókítà náà sí àhámọ́.

Adájọ́ Jumoke Kamson gba àbá olùpẹjọ́ yìí, tó sì pàṣẹ pé kí afurasí náà wà ní àhámọ́ fún ìgbà kan ná.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Karùn-ún ni Adájọ́ Kamson sún ìgbẹ́jọ́ sí láti tẹ̀síwájú lórí ọ̀rọ̀ náà

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here