Mà á nífẹ̀ẹ́ aráàlú lọ́kàn– Adeleke

Mà á nífẹ̀ẹ́ aráàlú lọ́kàn– Adeleke

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní báwo bá kì fúnni, níṣe ni à á kì padà fáwo.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Sẹ́nẹ́tọ̀ ademola Adeleke, ti sọ pé ìpè sí iṣẹ́ ni bí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà, ṣe dájọ́ pé òun ni ojúlówó Gómìnà tí ìlú dìbò yàn nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, lọ́dún 2022.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìdájọ náà wáyé nílùú Abùjá.
Nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ, nílé rẹ̀ tó wà nílùú Ẹdẹ, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Gómìnà Adeleke sọ pé Ọlọ́run ló gba ẹ̀rí òun jẹ́ nílé ẹjọ́, pé ìbò tó jẹ́ òtítọ ni wọ́n dì fún òun.

Adeleke ní òun gbóríyìn fún àwọn adájọ́ tó dá ẹjọ́ náà, nítorí wọn kò ṣe màgòmágó.

“Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti di àwòkọ́ṣe rere pé ìdájọ́ òdodo ṣì wà ní Nàìjíríà.”

Ó ní bí ilé ẹjọ́ ṣe fi ẹṣẹ̀ ìjọba òun múlẹ̀ jẹ́ ìpè fún iṣẹ́ àti fífún aráàlú ní èrè ìjọba àwa-ara-wa.

“Mo fi ara a mi jìn fún ìṣèjọba rere tó gbòòrò. Mà á sì jẹ́ Gómìnà tó ní ìfẹ́ aráàlú lọkan.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here