- Labour Party tẹ̀sìwájú APP kógbá ẹjọ́ ńlẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọtí ò tán àlejò ò lọ lọ̀rọ̀ dà látàrí ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́.Ìgbẹ́jọ́ tún ti bẹ̀rẹ̀ ni ilé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ nípa àwọn awuyewuye tó bá súyọ lẹ́yìn ìdìbò yóó ṣe gb ẹ̀sùn ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti olùdíje rẹ̀, Peter Obi lòdì sí Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn, Bola Tinubu.
Wámuwámu ni àwọn agbófinró dúró sẹnú ọ̀nà tó lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Abuja.
Bó ṣe yẹ kí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe kọ́kọ́ wáyé ni láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú APP ati Bola Ahmed Tinubu. Àmọ́, ẹgbẹ́ òṣèlú APP ti ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APP náà ti ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́ ọ́n, nítorí náà wọ́n ní kí ilé- ẹjọ́ fa ìwé ẹ̀sùn náà ya.
Agbẹjọ́rò fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ fún adájọ́ pé àwọn ṣì ń retí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú míràn tí wọ́n yóò sọ pé àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.
Agbẹjọ́rò fún àjọ elétò ìdìbò INEC ti ní àwọn kò takò ẹgbẹ́ òṣèlú kankan ti wọ́n bá ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.
Ní ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, wọn kò yọjú sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lónìí Ọjọ́rú torí pé wọ́n ti sún ìgbẹ́jọ́ tiwọn síwájú di Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀.
Láàrọ̀, ilé ẹjọ́ ni àwọn sún ìgbèjọ́ ti Labour Party síwájú sí aago méjì.
Bí àwọn agbófinró ṣe ń dúró láti mójútó ètò ààbò, bẹ́ẹ̀ náà ni orin oríṣi ń wáyé láti ẹnu àwọn tó ń se ìwọ́de.
Ohun tí àwọn olùwọ́de ń sọ ni pé, ki won jẹ́ kí ilé ẹjọ́ se ojúṣe wọn. Kí wọn má ṣe dùn ìkokò mọ́ àwọn ènìyàn.
Olùdarí ikọ̀ ọ̀hún, The Natives, Hon Smart Edward ni àwọn kò fẹ́ ki orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dà bìí Sudan, ìdí niyi tí àwọn fi ń se ìwọ́de.