Ọwọ́ tẹ àwọn arúfin tó kó igbó pamọ́ sí inú ìrẹsì

Ọwọ́ tẹ àwọn arúfin tó kó igbó pamọ́ sí inú ìrẹsì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí èèyàn bá mọ nǹkan an tọjú, kó má gbàgbé ẹni tó mọ ọn wá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí fún àwọn oníṣòwò igbó méjì kan, Aminu Saudi, ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta àti Abdulahi Sani, ẹni ọdún márùndínlógójì tọ́wọ́ àjọ tó ń gbógun ti lílò àti gbígbé òògùn olóró lorilẹ-ede yìí (NDLEA), tẹ nílùú Ọgbẹsẹ, nijọba ibilẹ Àríwá Akurẹ, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ igbó tí wọ́n kó sínú ìrẹsì.

Alukoro fún àjọ ọ̀hún, Fẹmi Babafẹmi, ló fìdí èyí múlẹ̀ nínú atẹjade kan tó fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún yìí.

Babafẹmi ní inú àpò ìrẹsì làwọn afurasí náà kó igbó ọ̀hún pamọ́ sí, kí wọ́n lè fi tan àwọn agbófinró jẹ pé ìrẹsì tòótọ ló wà nínú àpò náà, kì í ṣe igbó. Igbó tí wọ́n bá ní ikawọ àwọn èèyàn náà gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ọ̀hún ṣe sọ,ó tó bíi igba àti mọ́kànlá kílógíràmù (211 kg)

Ó ní àwọn aráàlú kan ló ta àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà lólobó tí wọ́n fi ri àwọn onígbó méjèèjì ọ̀hún mú l’Ọgbẹsẹ.

Ó ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹrin yìí, kan náà làwọn tún ṣàwárí oko igbó tó tó bíi sarè ilẹ̀ mẹ́fà nínú igbó kìjikìji kan nílùú Uṣo, níjọba ìbílẹ̀ Ọwọ.

Babafẹmi ní àwọn ti dáná sun oko ọ̀hún, tí àwọn sì rí i dájú pé gbogbo rẹ̀ di eérú kí àwọn tóó kúrò níbẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here