N’Íbàdàn,ó lé lógójì afurasí oníjìbìtì ayélujára tó kó sí gbaga àjọ EFCC

N’Íbàdàn,ó lé lógójì afurasí oníjìbìtì ayélujára tó kó sí gbaga àjọ EFCC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀,wọ́n níṣẹ́ tó bá le koko lọ̀lẹ yóó ṣe jẹhun.
Àwọn afurasí ọ̀dọ́ tó ń lu jìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára mẹ́rìnlélógójì ni àjọ EFCC ti fi kélé òfin mú ní Ìbàdàn olúìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú atẹjade tí àjọ EFCC fi léde lórí ìtàkùn ayélujára Twitter rẹ̀, àjọ náà ní agbègbè Apẹtẹ àti Bódìjà nipinlẹ Oyo ni àwọn ti mú àwọn afurasí ọdọ náà.

Lára ohun tí àjọ EFCC gbà lọwọ́ àwọn afurasí ọdọ tó ń lu jibiti ni ọkọ̀ bọgini mẹwa, kẹkẹ alupupu méjì, ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ mẹtaleladọta, ẹ̀rọ kọnputa mẹ́rin, gbohun gbohun Jbl kan, ẹ̀rọ eré ìdárayá playstation kan àti àwọn ohun èlò mìíràn.

Lára àwọn afurasí tí àjọ EFCC fi páńpẹ́ òfin mú ni

Alonge Timilehin Israel, Akinlade Tolulope Seyi, Taiwo Oluwatobiloba Daniel, Adesina Sodiq Ishola, Victor Paul Shedrack, Olawale Oladapo Olaleye, Muili Olamilekan Sodiq, Babalola Afeez Bolaji, Adeagbo Stephen Adegbenro, Ephraim Isaiah Joshua àti àwọn mìíràn tí àpapọ̀ gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàlẹ́lọ́gọ́ta .

Àjọ EFCC ṣèlérí láti gbé wọn lọlé ẹjọ́ nikete ti ìwádìí bá ti parí .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here