Afurasí agbébọn jí òṣìṣé ìjọba kan gbé lọ́nà márosẹ̀ Èkó si Ìbàdàn

Afurasí agbébọn jí òṣìṣé ìjọba kan gbé lọ́nà márosẹ̀ Èkó si Ìbàdàn

Fẹ́mi Akìnṣọlá

Àwọn afurasí agbébọn ti jí oṣiṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn kan Popoola Olasupo gbé lójú ọnà marosẹ ìpínlẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn.

Olasupo tó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ tó ń ṣe àbójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun ìyẹn, ‘Trace’ ni àwọn afurasí agbébọn náà gbé lágbègbè Eledumare sí Fidiwo lójú ọnà marosẹ Èkó sí Ìbàdàn.

Ìròyìn ní Ọlasupọ ń lọ sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àbọ̀ òwúrọ̀ ni, kí wọ́n tó jí i gbé lọ.

Lára àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó ń gbé e lọ sí ibi iṣẹ́ ṣàlàyé pé ṣàdédé ni àwọn agbébọn jáde láti inú igbó, “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n dàbọn bolẹ̀ tí wọ́n sì jí Olasupo nìkan gbé láàrin àwọn tí ó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé akérò ọ̀hún.

Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn DSP Abimbola Oyeyemi nígbà tí ó ń fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní,”àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń risi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti wà nínú igbó láti ṣe àwárí àwọn ajínigbé ọ̀hún “a sì ní ìgbàgbọ́ pé a ó rí wọn mú”.

“Ìpínlẹ̀ Ògùn kìí ṣe ibi tí àwọn ọdaràn ti le máa ṣọsẹ, gbogbo wọn lọwọ́ ọlọ́pàá máa tẹ, nínú kí wọ́n kúrò nílùú fún wa àbí ká fi imú wọn dánrin”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here