Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé gómìnà sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Adamawa

Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé gómìnà sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Adamawa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa, Ahmadu Umaru Fintiri, ti wọlé gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún sáà kejì.

Fintiri borí ìbò ọ̀hún pẹ̀lú ìbò tí iye rẹ̀ jẹ́ 430,861 nígbà tí ti olùdíje nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Sẹ́nẹ́tọ̀ Aisha Dahiru ní ìbò tí iye rẹ̀ jẹ́ 396,788.

Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta ọdún tí a wà yìí ni ètò ìdìbò Gómìnà ọ̀hún wáyé àmọ́ ìdìbò náà kò kẹ́sẹ járí, èyí tó mú kí wọ́n kéde àtúndì ìbò tó wáyé lópin ọsẹ tó kọjá.

Ètò ìdìbò ọ̀hún lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ṣáájú kí aṣojú INEC ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún tó kéde pé Aisha Dahiru, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Binani ló jáwé olúborí, èyí tó dá wàhálà sílẹ̀.

Àmọ́ aṣojú àjọ INEC ní ìpínlẹ̀ kò láṣẹ lábẹ́ òfin láti kéde ẹni tó jáwé olúborí nígbà tí wọ́n ṣì ń ka ìbò náà lọwọ́.

Ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé Aisha Dahiru, tí INEC kọ́kọ́ kéde ṣáájú yìí, ni yóó jẹ́ Gómìnà obìnrin àkọkọ ní Nàìjíríà, àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here