Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààwẹ̀ Ramadan ọdún 2023 dé, bẹ́ẹ̀ kúkú kẹ̀kẹ̀ rẹ̀ sì ti gbòde bí ọ ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú osù kẹta òǹkà ti òyìnbó yìí.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣọ yíyọ oṣù ààwẹ̀ Ramadan ní Nàìjíríà, kéde pé àwọn ti rí oṣù láwọn ìpínlẹ̀ kan.

Gbogbo wà la mọ̀ pé ọgbọ̀n, tàbí ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ọjọ́ gbáko ni ààwẹ Ramdan fi má ń wáyé, èyí tó mú kí ètò jíjẹ àti mímu jẹ́ pàtàkì nínú oṣù náà.

Kìí kàn án ṣe oúnjẹ lásán, ó sẹ kókó láti jẹ oúnjẹ àti mu omi lọ́nà tó yẹ, tó sì bá àgọ́ ara mu, kí okun lè wà fún ààwẹ gbígbà.
Oríṣìí oúnjẹ méjì ni jíjẹ lásìkò ààwẹ Ramadan, lójoojúmọ́.

Àwọn oúnjẹ náà ni wọ́n ń pè ní Suhoor (Yorùbá ń pè é ní Sààrì), àti Iftar (Ìṣínu) ní ìrọ̀lẹ́. Oúnjẹ fún Suhoor gbọdọ̀ jẹ́ èyí tó lè fún ọ ní okun láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́ tí ìṣínu yóó wáyé.

Àwọn nǹkan tó lè mú kí èèyàn já ààwẹ rẹ̀
Lásìkò àwẹ Ramadan, dandan ni fún àwọn Mùsùlùmí láti yago fún jíjẹ àti mímu, tó fi mọ́ àwọn nǹkan fàájì láti àárọ̀ di ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n ṣá, èèyàn lè já ààwẹ rẹ̀ nítorí àwọn ìdí kan.

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nínú Kùràánì, àwọn tó bá ní àìsàn tó sì nílò kí wọ́n ó lo òògùn, àwọn arúgbó, àwọn tó wà lẹ́nu ìrìnàjò, aláboyún, obìnrin tó ń fún ọmọ ní ọyàn, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé tí kò tíì bàlágà, lè yàn láti má gba àwẹ – papàá tó bá lè ní ipa tí kò dára lórí ìlera wọn.

Bákan náà obìnrin lè já ààwẹ rẹ̀ tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ lààrin àsìkò tó ń gbààwẹ̀

Àwọ n tí ọrọ̀ kan sì lè padà gba àwọn ọjọ́ ààwẹ tí wọ́n pàdánù lọ́jọ́ iwájú.

Ìlànà tí àwọn Mùsùlùmí ń gbà ṣínu yàtọ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan
Ní àwọn ibì kan, àṣà wọn ni láti ṣínu ní ilé olórí ẹbí wọn, tàbí ẹni tó dàgbà jù nínú ẹbí.

Oúnjẹ ní wọ́n ní àwọn kan fi má a ń ṣínu. Ṣùgbọ́n, ní àwọn orílẹ̀-èdè bí i UAE, oúnjẹ onípele mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi ń ṣínu.

Oṣù Ramadan gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí oṣù ọlọ́rẹ
Lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí ló má a ń ṣe iṣẹ́ àánú àti ìtanilọ́rẹ bí i fífún àwọn tí kò ní, ní oúnjẹ àti owó.

Ìgbésẹ̀ yìí, Zakat, jẹ́ ọ̀kan lára òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam dúró.

Ọdún ìtúnu ààwẹ, Eid, ló má a ń gbẹ̀yìn Ramadan
Eid al-Fitr, tó túmọ̀ sí ìtúnu ààwẹ, tàbí àsè ìṣínu ààwẹ, má a ń wáyé fún ọjọ́ mẹ́ta tó kẹ́hìn ààwẹ Ramadan.

Ní kété tí wọ́n bá ti rí oṣù tuntun lójú ọ̀run ni ìtúnu ààwẹ má a ń bẹ̀rẹ̀.

Èyí tó mú kí ọjọ́ ìtúnu yàtọ̀ láti orílẹ-èdè kan, sí orílẹ-èdè míìràn ní àgbáyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ju ọjọ́ kan sí méjì tó má a ń wà láàrin wọn.

Ǹ jẹ́ ní báyìí tí àwọn Mùsùlùmí jákèjádò Orílẹ̀ yìí ti wà ní ìkáraró, ó wá yẹ kí à ṣàmúlò ẹ̀kọ́ inú oṣù ààwẹ̀ ọ̀hún, láti fọ tọkàntara wa mọ́ kangá kúò níbi àwọn ìwà burúkú tó lè tapo sí àṣọ àlà a wa gẹ́gẹ̀ bí i ẹlẹ́sìn mùsùlùmí.
Ó yẹ kí á gbìyànjú nawọ́ ìfẹ́ sí àwọn èèyàn ju tàtẹ̀yìnwá lọ ,yálà ni àyíká a wa tàbí ní àwọn agbègbè mìíràn tí a bá ti gbọ́ pé wọ́n nílò ìrànwọ́,kí à sì sà fún ṣekárími, kí láádá a wa lè kún kẹ́kẹ́.
Kí Ọlọ́run Ọba Àlekèọlá gbàá lẹ́sìn lọ́wọ́ ọ wa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here