Inú mí dùn pé ipò ààrẹ ti padà si ìhà Gúùsù Orílẹ̀ yìí – Nyesom Wike

Inú mí dùn pé ipò ààrẹ ti padà si ìhà Gúùsù Orílẹ̀ yìí – Nyesom Wike

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní kú u iṣẹ, ní-ín mórí oníṣẹ́ ẹ́ yá.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó dìbò láti dá agbára padà sí Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Wike ní inú òhun dùn pé òpin ẹnu àwọn tó lòdì sí kí ipò ààrẹ máa yí láti ẹkùn kan sí òmíràn ti gbẹ nu dakẹ báyìí pẹ̀lú bí Bọ la Ahmed Tinubu ṣe borí ní ìdìbò sípò ààrẹ.

Bọla Tinubu tó borí pẹ̀lú ìbò tó lé ní mílíọ̀nù méjọ ló wá láti ìhà Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Wike ọ̀hún ló sọrọ lásìkò tí ó darapọ̀ mọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde láti ṣí ilé epo 5,000,000-litre Aviation Fuel Dispensing Depot ní agbegbe pápákọ̀ òfurufú ní Alakia, ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ṣáájú ìdìbò sípò ààrẹ náà ni Wike ti fi ìdí rẹmi nínú ìdìbò abẹ́lé láti díje du ipò ààrẹ.

Lẹ́yìn náà ni Wike ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi a àìdùnú rẹ hàn sí bí Atiku Abubakar sẹ jáwé olúborí nínú ìdìbò náà.

Bákan náà ni Wike fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde fún bí ó ṣe ṣe àtìlẹ́yìn fún kí agbára ìjọba padà sí Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here