Àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, àmì Ọlọ́run wà lára rẹ̀ – Ọọ̀ni

Àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, àmì Ọlọ́run wà lára rẹ̀ – Ọọ̀ni

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀, Kábíyèsí Ẹnitan Ogunwusi Ọjaja Kejì ti kan sáárá sí ìjáwé olúborí Bọla Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ọọ̀ni Ogunwusi nígbà tó ń kópa lórí ètò ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán TVC ṣo pe àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu nítorí náà ló ṣe jáwé olúborí.

Ó ní àwọn àmì Ọlọ́run kan wà lára Tinubu tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún-ún láti rí i pé ó gbégba orókè níbi ìdìbò náà.

“Èyí fi hàn pé àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, tó ní àwọn ẹ̀mí mímọ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ ire fún un láti dé ipò náà.”

“Ọlọ́run dá Tinubu lárà ọ̀tọ̀ ni tó jẹ́ wí pé ó ní iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run fẹ́ fi jẹ́ fún àwùjọ ni. ”

Ọọ̀ni ní òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìránṣé Ọlọ́run kan ń bá Tinubu gbé ló fi jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tó jẹ́ wí pé àwọn tí kò fẹ́ pọ̀ ju àwọn tó fẹ nípò lọ.

Ṣáájú ni Ọọ̀ni ti ránṣẹ́ ìkíni kú oríire sí Tinubu tó sì rọ àwọn olùdíje yòókù tó fìdí rẹmi láti gba kádàrá, kí wọ́n ṣe àrídájú rẹ̀ pé àláfíà jọba ní Nàìjíríà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here