Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe yìnbọn pa aya mi ní àgọ́ ìdìbò rẹ̀”

“Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe yìnbọn pa aya mi ní àgọ́ ìdìbò rẹ̀”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ètò ìdìbò sípò Ààrẹ àti sáwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìlú Abuja ti wá, tó sì ti parí lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà, INEC ti kéde ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.

Àmọ́ fún ìdílé Owie, ètò ìdìbò náà dá ọgbẹ́ ọkàn sílẹ̀, tí kò lè tán sí ìgbé ayé wọn títí láé.

Ọ̀pọ̀ ìròyìn ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ àmọ́ àwọn àwòrán àti fídíò kan ṣàfihàn pé làásìgbò wáyé ní àwọn agbègbè kan lásìkò ìbò náà.

Lára irú ibi tí wàhálà bẹ́ẹ̀ ti wáyé ni ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edo.

Elizabeth Owie, ẹni ọdún méjìlélógójì gbéra nílé rẹ̀ láti lọ dìbò lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni agbègbè Ogheghe, ìjọba ìbílẹ̀ Ikpoba Okha, ìlú Benin, ìpínlẹ̀ Edo.

Àmọ́ kò padà sí ilé rẹ̀ láàyè, bí ọta ìbọn ṣe bá a, tó sì ṣekú pa á.

Ọkọ Elizabeth, Owie Osadebamwen sàlàyé fún akọròyìn bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, tó fi di ẹni tí kò láya mọ́ lójijì.

Ó ní ọmọkùnrin mẹ́ta ni àwọn ti bí, tí ìgbéyàwó náà kò bá sì pé ọdún mẹ́wàá nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún yìí, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bá wáyé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here