Àgbà Alfa ni ọkọ ọ̀ mi n‘Ìbàdàn, kàyéfì ni pé wọ́n ká orí àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́fíìsì rẹ̀”

Àgbà Alfa ni ọkọ ọ̀ mi n‘Ìbàdàn, kàyéfì ni pé wọ́n ká orí àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́fíìsì rẹ̀”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbàlagbà ní bí èèyàn bá ń yọ́ ilẹ̀ ẹ́ dà, dájú sáká ohun burúkú a máa yọ́rú u won ṣe, àṣamọ̀ yìí ló díá fún bí
ọwọ́ Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣe tẹ afurasí mọ́kànlá pẹ̀lú orí gbígbẹ mẹ́sàn-án, orí tútù kan, ìfun àti àwọn ẹ̀yà ara èèyàn mìíràn nílùú Ìbàdàn.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adewale Osifeso ló kéde ọ̀rọ̀ náà nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí ọ̀hún níbi tí wọ́n sá pamọ́ sí ní agbègbè Orita Aperin.

Osifeso ní àwọn afurasí náà ló ń ṣe oko òkòwò orí àti ẹ̀yà ara èèyàn fún àwọn ohun ètùtù.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá fikún un pé “Àwọn èèyàn mọ́kànlá náà ló ti jẹ́wọ́ pé àwọn kópa nínú okoòwò náà nígbàtí a fi ọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú u wọn.

“Wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn máa ń lọ hú àwọn orí gbígbẹ náà ní itẹ́ òkú káàkiri.

“Bákan náà ni wọ́n jẹ́wọ́ pé orí tútù àti àwọn ẹ̀yà ara èèyàn tí a kà mọ́ wọn lọ́wọ́ ló jẹ́ ti ọ̀kan lára wọn, tó ń jẹ́ Amuludun.

Àwọn afurasí náà ní Amuludun ló pa ẹni tó ni orí náà, tó sì bẹ́ orí ọ̀hún bó se pa ẹni náà tán, à mọ́ tí afurasí náà ti sálọ.”

Ọ̀kan lára àwọn afurasí tí ọwọ́ tẹ̀ ló jẹ́ ìyàwó Alfa, ẹni tó jẹ́ olórí àwọn ọ̀daràn náà, tí òun náà ti sálọ, sọ pé òun kò mọ̀ pé ọkọ òun ní orí èèyàn nínú ọfiisi rẹ̀ nítorí alfa mùsùlùmí ni òun mọ̀ ọ́ sí, tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu.

Ó sàlàyé pé òun lọ sí ọọ́fíìsì ọkọ òun láti gba owó oúnjẹ ni àwọn ọlọ́pàá wọlé dé láti wá tú ọọ́fíìsì , tí wọ́n sì rí orí èèyàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here