Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀, ó yẹ kí á kíì kú ewu.
Iléeṣẹ́ Ààrẹ Amẹ́ríkà ti kéde pé ààrẹ orílẹ̀ èdè náà, Joe Biden ti ṣiṣẹ́ abẹ láti yọ àìsàn jẹjẹrẹ ara tó ń yọ ọ́ lẹ́nu dànù.

Dókítà Biden ní pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ yìí, Biden kò nílò ìtọ́jú kankan mọ́ lórí àìsàn jẹjẹrẹ.

Àmọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ìtọ̀jú awọ ara rẹ̀ láti mójútó ìlera rẹ̀.

Nínú oṣù Kejì ọdún yìí ni Biden tún àyẹ̀wò ṣe, tí iléeṣẹ́ ààrẹ sì ní ara rẹ̀ ti le, tó sì ti gbádùn láti máa bá iṣẹ́ ìlú lọ.

Dókítà Kevin O’Connor nínú àkọọ́lẹ̀ kan tó tẹ àwọn akọ̀ròyìn lọ́wọ́ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kejì ni wọ́n yọ àìsàn jẹjẹrẹ náà kúrò ní àyà Biden ní ilé ìwòsàn “Reed National Military Medical Center ” èyí tó wà ní ìta Washington DC.

“Kò nílò ìtọ́jú kankan mọ́ àti pé ibi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ náà ti ń san”, O’Connor sọ.

Àkọọ́lẹ̀ náà fi kún-un pé irú àìsàn jẹjẹrẹ tí wọ́n bá lára ààrẹ náà ni -basal cell carcinoma- èyí tí kìí sábà ràn mọ́ ìbòmíràn.

Basal àti squamous ni irúfẹ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara tó wọ́pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí àjàkálẹ̀ àrùn àti àmójútó rẹ̀, CDC ṣe sọ.

Àjọ “Skin Cancer Foundation” ní èèyàn mílíọ̀nù 3.6 ló máa ń ní àìsàn náà ní ọdọọdún. Ó máa ń pẹ́ kó tó dàgbà, ó ṣe é wòsàn, tí kò sì ní bá ẹya ara jẹ́ tí wọ́n bá tètè ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Ní oṣù Kìíní ọdún, ìyàwó ààrẹ, Jill Biden náà ṣiṣẹ́ abẹ láti yọ àìsàn jẹjẹrẹ mẹ́ta ṣùgbọ́n tí ọ̀kan nínú wọn padà di “basal cell carcinoma”.

Kí Biden tó di ààrẹ ló ti ń yọ àìsàn jẹjẹrẹ ẹ̀yà ara kúrò lára rẹ̀.

Biden àti ìyàwó rẹ̀ ti ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sọ̀rọ̀ lórí àìsàn jẹjẹrẹ tí wọ́n sì ń tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà lórí rẹ̀.

Ní ọdún 2015 ni ọmọkùnrin wọn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ọpọlọ.

Àwọn ènìyàn ènìyàn ti ń retí bóyá Biden máa kéde láti tún du ipò ààrẹ fún sáà kejì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here