̀ Ó kọtí ọ̀gbọin sí àwọn babaláwo Ilé Ẹjọ́ Gíga
– IPAARO OWO: Emefiele da ipaya ati rogbodiyan silu
– APC n korin anjuwon o see wi lejo, won ni tori Tinubu ni oro naira ati epo se dogun-dode
Paahee si n joba ni oile ede yii latari ipawoda to ba naira, lati owo banki to ga julo, iyen Central Bank of Nigeria, CBN.
Oro atunse lori naira naa to bere bi ere ti di nnkan nla, to n mu laasigbo ba ilu, ti ko si je ki tomode-tagba moo do ti won yoo da orunla si mo.
Oga Agba ni CBN, Ogbeni Godwin Emefiele, pelu Aare Muhammadu Buhari ni won mo ibi ti won di kinni naa si.
Awon mejeeji ni iyipada n ba awo N1,000, N500 ati N200 lati ba awon alakatakiti terrorists to ti ko owo pamo ja, lati ma je ki owo to le fa esuke ba oro aje po ni ita, ati lati ma je ki awon oloselu o ri owo ra ibo lasiko idibo to n bo.
Leyin wi pe opo eniyan ro pe ejo lowo ninu, ose bii marun-un pere ni Central Bank fi ni ki awon eniyan da naira atijo pada. Eyi fa waduwadu, tori ko si eni to fe ki owo di lunte moo un lowo.
Ibi ti wahala ti wa de baye ni pe owo tuntun to ye ki awon eniyan maa ri gba ni banki ko si nibe, ti ero alatagba Internet naa n ja bute bute, ti ko si je ki awon eniyan maa ni isoro lati lo banki olofurufu.
Nnkan ti daru debi pe naira ni awon eniyan fi n ra naira, paapaa lodo awon to n sise POS, ti won n gba bii egberun meji naira – tabi ju bee lo – lori N10,000.
A ti ri eni to ku sori ila nibi ti won ti fe gba ATM.
Rogbodiyan ti n be sile kaakiri, ti awon eniyan kan si ti gbemii mi ni Ibadan ati Edo.
Bee, idibo lo ku ojo meloo yii, to si je pe epo petrol naa ti won bii imi egungun.
Idi niyi to fi ya awon eniyan lenu pe Aare Buhari je ki wahala naa tan kaye bee, lai gbe igbese gidi kan to moyan lori.
Bee, bi awon eniyan kan se n ro pe Tinubu ni awon ota ikoko re ni Abuja, ti won n pe ni cabal fe fi ba loja je, Buhari si n polongo pe tie – ti Jagaban – loun n se. O ni obinrin to loyun, toKO re lo n se. Koda, o n tele Tinubu lo si awon ipinle kan fun kampeeni.
Gomina Ipinle Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, so ni tire pe awon cabal lo wa nidii yanponyanrin to n jalu lori epo ati naira.
Sibesibe, awon kan ni Buhari le ma ni nnkan ti ko dara lokan si Tinubu, ko kan gbagbo ninu ohun ti Emefiele ba so fun un.
Pabambari sele lojo Alamisi TO LO LOHUN, nigba ti Buhari kede pe N500 ati N1,000 ti di owo aina ni Naijiria. Eyi lodi si ohun ti ile ejo giga Supreme Court pa lase pe ki gbogbo owo si w ani nina titi ejo ti awon gomina kan bii El-Rufai ati Yayaha Bello gbe was siwaju re yoo se lojutuu.