Bàbá àti ọmọ yanṣẹ́ adigunjalè láàyò

Bàbá àti ọmọ yanṣẹ́
adigunjalè láàyò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Onírúurú ìwà èérí sá lá ó máa rí gbọ́ lákàtà àwọn èèyàn láabi
Ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣàníyàn láti fi iṣẹ́ rere lé ọmọ wọn lọ́wọ́, à mọ́ ní ti bàbá arúgbó ẹni ọdún márùúndínlọ́gọ́rin tí wọ́n lórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Weniwọn Abioro yìí, olè jíjà pọ́ńbélé lòun kọ́ ọmọ bíbí inú ẹ̀, oko olè ọ̀hún sì ni wọ́n ti mú òun atọmọ rẹ̀, Zaccheous Abioro, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, wọ́n ti wà ní ìgbèkùn àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ báyìí.

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ìṣẹlẹ yìí wáyé lọjọ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdílógún, oṣù Kejì yìí, nígbà táwọn afurasí náà yọ́ kẹ́lẹ́ wọnú oko tó jẹ́ ti Alaaji Moruf Kaka, èyí tó wà nílùú Ihunbọ, níjọba ìbílẹ̀ Ipokia, ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Àwọn aládùúgbò kan tó rí wọn níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti jáde lóko ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n ti jí àwọn dúkìá ẹni ẹlẹ́ni tán, ni wọ́n pariwo olè lé wọn lórí, wọ́n ṣì mú wọn, ni wọ́n bá ké sáwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò So-Safe lórí aago.

Nígbà tí wọ́n dé bẹ, wọ́n rí àwọn ẹrù tí wọ́n jí, lára ẹ̀ ni ìwé ilẹ̀ méjì, èròjà ọkọ̀ kan, àti àwọn wíńdò alumí tí wọ́n yọ férémù rẹ̀ gbogbo.

Ǹ jẹ́ kí ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ẹrù tí wọ́n jí kó yìí ṣe, wọ́n ní àwọn fẹ́ lọ tà á fáwọn ṣalẹ̀-ṣalẹ̀ tí wọ́n máa ń ràá ni, wọn tiẹ darukọ kọsitọma kan ti wọn lo maa n ra alumi lọwọ awọn, Ọgbẹni Bapa Madaki, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n.

Kíá làwọn ẹ̀ṣọ́ So-Safe ti wá òun náà kàn, tí wọ́n sì gbé e janto.

Wọ́n láwọn afurasí náà ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ làwọn ń jalè, kí wọ́n ṣàánú àwọn.

Alukoro ilé-iṣẹ́ So-Safe sọ pé àwọn ti fa àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ó ní iṣẹ́ ìwádìí ń tẹ̀síwájú lórí i wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here