Bi e ba n gbo kangokango bayii, agogo ibo lo n ro o.
Eyin ni ibo Aaare to n waye lonii, ojo keedogbon osu keji yii – February 25, 2023.
Gege bi awon omo Naija se n wa olori miran, bi a ko ba ni tan ara wa, o dabi alailera eniyan to n wa dokita tabi adagunse miran leyin opolopo odun ti ara re ko ti ya, ti oniruuru onisegun si ti n ti i si ara won ni.
Aare Ologun, Aare alagbada ti n ti i si ara won lati 1960. Sibesibe, bo se wa lo wa, tabi ko tun buru ju bee lo lawon apa ibi kan.
Lowolowo yii, owo Muhammadu Buhari ni Naija ti n gbawosan lati 2015. O ti koko wa bi Ologun, ko to wa pada bii alagbada.
Bo seere, bi ko seere, orile ede kan oun naa ni gbogbo wa wa y ii.
Sugbon ohun to se koko julo ni pe laarin Asiwaju Bola Tinubu (All Progressives Congress), Atiku Abubakar (Labour Party), (Peter Obi) Labour Party ati Rabiu Kwakwaso (NNPP) ni o jo pe olori yoo ti jade.
Bo tile je pe awon ibo elerefee kan lori Intaneeti n so pe Obi n gbegba oroke, ti Atiku naa kii si se ei ti eni kan le fowo ro seyin, opo eniyan ri Tinubu gege bi eni to le la awon to ku julo.
Lara ohun ti iru awon eni bee n wo ni bi o se je pe o moo po eniyan to se koo kaakiri Naijiria, o ni iriri ati owo to le fi hu ibo jade, awon gomina to le ni ogun lo wa leyin re. Ni Oke Oya ti ibo si o si ju naa, Tinubu ni awon gomina to lenu ti won n sise fun un karakara.
Lara won ni Nasir El-Rufai ti Kaduna ati Abdullahi Ganduje ti Kano.
Sugbon sa o, yoo kun ni, yoo fa ni o, oni lonii je!