Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní tí omọ bá gbọ́n gbọ́n-ọn kúkú lẹ́ẹ̀rùn, ìyá a rẹ̀ á gbọ́n gbọ́n àti sin-ìn sí padò.
Ní báyìí, adarí àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu ti ní ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti jí ìbò tàbí da ètò ìdìbò rú yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu, nítorí pé àwọn agbófinró yóò fi ìyà tó tọ́ jẹ onítọhún.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu sọ èyìí lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Àbújá ní gbọ̀gàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) tó wà nílùú Àbújá.

Gbọ̀ngán ICC yìí ni wọn yóò máa lò láti máa kó gbogbo èsì ìbò tó bá ń wáyé ní gbogbo ìpìnlẹ̀ jọ.

Bákan náà, gbọ̀ngàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) yìí ni wọn yóò lò láti kéde ẹni tó bá jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Ààrẹ ọ̀hún.

Lára àwọn tó wà níbí ìpàdé náà ni adarí ilé isẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà Usman Alkali Baba, àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè òkèèrè, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn akọ̀ròyìn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here