Ilẹ̀ rírì mìíràn tún ṣọṣẹ́ ní Turkey, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tún ṣèṣe !
Fẹ́mi Akínṣọlá
Hun-ùn hún, à fi kí Ọlọ́run sá à máa kó wa yọ nínú ewu gbogbo. À ń jèkuru ọran kó tán, lọ̀rọ̀ ilẹ̀ ríri ní ìlú yìí ọ,bí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì mìíràn tó wọlé tó jìn tó ìwọ̀n 6.4 tún ti ṣọṣẹ́ ní ẹkùn gúúsù orílẹ-èdè Turkey, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ rírì tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní orílẹ̀èdè náà wáyé.
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀èdè náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Àwọn óṣojúmikòró sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Antakya.
Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kejì ni ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì wáye gbẹ̀yìn níbẹ̀ níbi tí ènìyàn 44,000 ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní Turkey àti Syria.
Mayor ìlú Hatay ní gúúsù Turkey ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló há sábẹ́ ilẹ̀.
ààrẹ Turkey ní kò dín ní ènìyàn mẹ́jọ tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tuntun yìí.
Àwọn aláṣẹ Turkey ní kò dín ní ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó wáyé ní ọjọ́sí dá ìbẹ̀rù sí lára àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ BBC tó wà ní agbègbè náà ní èyí tó wáyé lónìí lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n gbúròó rẹ̀ ní Syria, Egypt pati Lebanon.
Kò ì tíì sí àrídájú kankan báyìí bóyá ẹnikẹ́ni bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ àti iye ìjàmbá tó fà.
Muna Al Omar sọ fún Reuters pé òun wà lábẹ́ àtíbàbà kan ni òun gbọ́ tí ilẹ̀ rírì náà tún wáyé.
Ó ní òun lérò wí pé lábẹ́ ẹsẹ̀ òun ni ilẹ̀ náà yóò ti lanu ni bó ṣe mú ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún méje dúró ṣinṣin.
Akọ̀ròyìn AFP tó wà ní agbègbè náà ní inú fu àyà fu ni àwọn ènìyàn tó wà ní Antakya wà báyìí pẹ̀lú ọṣẹ́ tí èyí tó wáyé kọjá ti dà sí wọn lára.
Iléeṣẹ́ AFP jábọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ń pè fún ìrànlọ́wọ́.
Ali Mazlum ní òkú àwọn ẹbí òun tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó kójá lọ ni òun ń wá kí òmíràn yìí tó tún wáyé.
Ní Syria, àjọ tó ń mójútó ààbò ìlú ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló farapa bí àwọn ilé ṣe ń dàwó.