Àwọn ọmọlooku láwọn kò gba owó àtijọ, ni wọn bá gbé POS kalẹ̀ fáwọn èèyàn

Àwọn ọmọlooku láwọn kò gba owó àtijọ, ni wọn bá gbé POS kalẹ̀ fáwọn èèyàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ burúkú sòde kánrin, Ó dà bí ẹni pé ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ ń túbọ̀ fẹsẹ̀ rinlẹ̀ síi lojoojúmọ́ ni o pẹ̀lú ìsesí àwọn èèyàn àwujọ lásìkò yìí.
Ọrọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín, à fi bí àwàdà kẹríkẹrì ni ọ̀rọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé kan ní ìpínlẹ̀ Anambra, tí wọ́n gbé ma-n-ṣí-ìn-nì pélébé tí wọ́n fi ń gbowó, POS, sórí i tábìlì, wọ́n ní kí àwọn tí wọ́n wá á bá wọn kẹ́dùn èèyàn wọn tó kú lè ríbi fún wọn lówó. Eléyìí kìí ṣe ijokoo aláàáfà tàbí àwọn pásítọ̀ Kankan o. Ètò ìsìnkú ni wọ́n ń ṣe, fúnra àwọn mọ̀lẹ́bí ni wọ́n sì sọ ọ́ di mímọ̀ fáwọn èèyàn tó wà níkàlẹ̀ níbẹ̀.

Lásìkò tí ètò ìsìnkú bàbá wọn àgbà ọhún ń lọ lọ́wọ́ làwọn mọ̀lẹ́bí tí kéde pé àwọn ò fẹ́ owó àtijọ́, kí àwọn tí kò bá sì ní owó tuntun lọwọ́ mú káàdì ATM wọn láti fi sanwó tí wọ́n bá fẹ́ fún àwọn. Wọ́n ní kò sí àwíjàre fẹ́nikẹni láti ma ṣe fi owó sílẹ, kí ẹni tí kò bá lówó tuntun ṣe tiransifáà, àbí kí wọ́n fi POS sanwó. Bákan náà ni wọ́n tún kọ nọmba àkáùǹtì, nítorí àwọn ti ATM wọn kò bá sí pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n lè fowó ṣọwọ́ sí wọn láti orí fóònù wọn.

Pẹ̀lú èdè Íbò wọn yìí náà ni ọkùnrin kan nínú ẹbí ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún bí wọ́n ṣe yẹ́ wọn sí, lẹ́yìn náà ló rọ̀ wọ́n pé, “ látàrí bí orílẹ-èdè yìí ṣe rí báyìí, tí ìjọba sì ń kéde owo-ina ori ẹrọ ayelujara ti ko ni i ṣe pẹlu owo beba, a ti ṣeto ẹrọ POS ati a àkáùǹtì báńkì fún àwọn tí kò bá ní owó tuntun lọ́wọ́. Ẹ lọ sí àwọn orí tébùrù káàkiri, ẹ ó rí POS níbẹ̀, ẹni tí kò bá sì ní káàdì ATM lọwọ́ , àkáùǹtì nọmbà la kọ síbi bébà ńlá tá a so kọ yẹn. Mò lérò pé ọrọ̀ mi yé wa? Ẹ ṣeé o.

Èyí wáyé látàrí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe léde pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) Náírà ti di kọ̀ǹdẹ̀ , kò ní í jẹ́ níná mọ́, kí àwọn tí wọ́n bá ní in lọ́wọ́ sì kó o lọ sí báńkì àpapọ̀ ìpínlẹ̀ wọn, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tẹ̀lé àlà kalẹ̀ ètò tí báńkì àpapọ̀ fún wọn.

Nínú fídíò tí wọ́n gbé sórí ẹ̀rọ ayélujára yìí, bíi ọ̀nà mẹ́ta tí wọ́n gbé tebu kalẹ̀ sí ni wọ́n kó ma-n-síìnì ìyẹn ẹrọ POS méjì méjì sí, àwọn tí wọ́n jókòó síbẹ̀ láti dá àwọn èèyàn lóhùn sì jókòó tì í gbágbágbá bíi ẹni pé wọ́n wà nídìí ọjà a wọn ni. Owó péréte ló wà nínú tíréè nlá kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti máa fi gbowó, ó jọ pé inú àpò báńkì ọ̀hún ni púpọ̀ èèyàn ń sanwó sí, nígbà tí kò tí ì sí owó rẹpẹtẹ nílùú.

Níwájú tébùrù kọ̀ọ̀kan yìí náà ni wọ́n tún so bébà fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan si, orukọ, nọ́ńbà àti irú bánkì tí wọ́n máa fowó ránṣẹ sí, ni wọ́n kọ síbẹ̀, wọ́n sì gbé òkúta lé e nítorí kí atẹ́gùn má ba à gbé e lọ. Níwájú fọ́tò bàbá tó kú yìí bákan náà, wọ́n tún gbé àwo ìjẹun kékeré ayé àtijọ́ kan síbẹ̀, fún ànfààní àwọn tí wọ́n bá fẹ́ sọ owó síbẹ̀

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here