Akérédolú sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Emfiele, lórí ìṣòro àìsí owó náírà tuntun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbàlagbà ní bí ọrọ ńlá kò bá tí ì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi àròyé.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú, SAN, ti ké sí Ààrẹ Muhammadu Buhari kó jáwọ nínú ìlànà owó náírà tuntun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú.
Akérédolú tún bu ẹnu àtẹ́ lu Gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ìyẹn Godwin Emefiele fún ìlànà owó náírà tuntun náà.
Gómìnà Akérédolú ló sọ ọrọ̀ náà nínú atẹjade kan tó fi léde lójú òpó Facebook rẹ .
Nínú atẹ̀jáde ọ̀hún ló ti bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Buhari bo ṣe fòfin de niná owó ₦500 ati ₦ 1000 àtijọ́.
Tí ẹ kò bá gbàgbé, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Buhari bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀, níbi tó ti sọ pé òun ti pàṣẹ fún CBN kó kó ₦200 àtijọ́ síta kí àwọn aráàlú ṣì máa ná a títí di ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹrin, ọdún yìí.
Àmọ́ o ní ₦500 àti ₦1000 àtijọ́ kìí ṣe owó tí àwọn aráàlú lè máa ná mọ́.
Akérédolú ní àṣẹ tí Buhari pa nínú ọrọ̀ rẹ̀ sí àwọn aráàlú lórí owó tuntun náà kò bójúmu.
Àtẹ̀jáde náà ni “Mo fẹ́ fi àkókò yìí bẹ Ààrẹ Muhammadu Buhari kó wu ìwà bàbá, kó sì fòpin sí ìlànà owó náírà tuntun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú yìí .”
“ Láì sí àníàní, Gómìnà CBN, Emefiele ti ṣe àṣìṣe nípa ìlànà owó náírà tuntun náà, ìlànà ọ̀hún sì ti kùnà .”