Nítorí oúnjẹ tó pé̩ Azeez dáná sun ìyàwó ẹ n’Íbògún

Nítorí oúnjẹ tó pé̩ Azeez dáná sun ìyàwó ẹ n’Íbògún

 

Lati ọwọọ Adefunkẹ Adebiyi

Ẹka to n ri si i ipaniyan ni ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ bayii pe ki wọn gbe ọkunrin yii, Azeez Hassan lọ. Eyi waye latari bi ọkunrin naa ṣe da epo bẹntiroolu lu iyawo ẹ, Ọlayinka, to si ṣana si i lara nitori ounjẹ to ni obinrin naa ko tete gbe foun, iyẹn nile wọn to wa n’Ibogun, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi fi sita lọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2023 yii ṣe ṣalaye, ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 niṣẹlẹ naa waye. Ṣugbọn bi Azeez ṣe ri i pe oun ti daran lo ti fẹsẹ fẹ ẹ ti ẹnikẹni ko si ri i mọ.

SP Oyeyẹmi ṣalaye pe Baba Ọlayinka tọkọ rẹ dana sun lo waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ibogun lọjọ naa, pe ọkọ ọmọ oun da epo bẹntiroolu si i lara, o si sọ ina si i nitori ọrọ ti ko to nnkan. Ati pe ileewosan kan lawọn sare gbe ọmọ naa lọ fun itọju, n’Ibadan.

Ifisun Baba iyawo lo jẹ kawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe ri Azeez mu,nigba to si di ọjọ kejilelogun oṣu kin-in-ni ọdun 2023 yii, ọwọ wọn ba a, eyi si jẹ oṣu kẹta geerege lẹyin to sa lọ.

Ninu alaye Azeez to dana sun iyawo ẹ, o sọ fawọn ọlọpaa pe orilẹ-ede Olominira Bẹnẹ loun sa lọ lẹyin iṣẹlẹ naa. O jewọ fun wọn pe loootọ loun dana sun iyawo to ti bimọ kan foun naa, ṣugbọn ẹjọ oun naa kọ, Eṣu lo jẹbi.

Azeez, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46), ṣalaye pe oun ni kiyawo oun dana ounjẹ foun lọjọ naa ni,ni ko ba dahun,lo ba n fi oun fọ aṣọ lọ.

O ni aṣọ to n fọ lai ba oun gbe ounjẹ wa naa lo bi oun ninu, nitori ebi to n pa oun lọjọ naa legba kan jọrin lọ. O ni nigba ti Ọlayinka ko si yee fọṣọ, ti ko foun lounjẹ ni ibinu ru bo oun loju. Loun ba gbe epo bẹntiroolu nilẹ, loun da a si i lara, oun si ṣana si i.

Bẹẹ ni iyawo Azeez bẹrẹ si i jona, ọkọ rẹ to dana sun un si nana papa bora foṣu mẹta gbako kọwọ ọlọpaa to o ba a.

Awọn ọlọpaa tilẹ beere lọwọ ẹ, pe ta a lo ni aṣọ tiyawo naa n fọ lọjọ yii, ọkunrin naa si dahun pe aṣọ oun ni.

Iwa to le gba ẹmi lẹnu eeyan ni baale ile naa hu, eyi ni ọga ọlọpaa ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ sẹka to n gbọ ẹjọ awọn aṣekupani.

Lati ibẹ ni iwadii yoo ti tẹsiwaju, ti wọn yoo si gbe Azeez to dana sunyawo ẹ lọ sile-ẹjọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here