Ikú tún ti mádẹ́rìínpòṣónú mí-ìn lọ láti ìpínlẹ̀ Kano

Ikú tún ti mádẹ́rìínpòṣónú mí-ìn lọ láti ìpínlẹ̀ Kano

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hùn! Ikú ò dọ́jọ́, bẹ́ẹ̀ làrùn ò dóṣù, ní báyìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ló ń ṣe ìdárò ọ̀dọ́kùnrin adẹ́rìínpòṣónú tó gbajúmọ̀ lórí ayélujára Tiktok ní ìpínlẹ̀ Kano báyìí.

Kamal Aboki ló máa ń pa àwọn èèyàn lẹ́rì-ín ní àríwá Orílẹ̀ yìí.

Ó daláìsí níbi ìjàǹbá ọkọ́ tó wáyé ní Kano lẹ́yìn tó dé láti ìpínlẹ̀ Borno.
Tishama Cemetery ni ilé ìkẹyìn tí wọ́n sin Kamal Aboki sí ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí èyí tó wà ní ìlú u Kano

Usman Iliyasu ẹ̀gbọ́n olóògbé nígbà tí ó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àbúrò òun riìrìn àjò lọ sí ìlú u Maiduguri.

Ó ní òun pe Kamal ní bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́r tí ó sì ṣàlàyé pé òun wà nínú ọkọ̀ tí óun ń gbé bọ̀ padà sí Kano.

  1. Usman ní ẹnìkan lọ túfọ̀ ikú àbúrò òun fún ìdílé wọn láti ìgbà náà ni ìyá àwọn ti wà nínú ìpòrúùru ọkàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here