Ilorin Grammar School gba ìyá àgbà Ajayi Folashade ,ẹni àádọ́ta ọdún wọlé sí Jss 2
Ọrẹ Òtítọ́jù
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ìgbà a bá jí n làárọ̀ ẹni, bẹ́ẹ̀ kò sígbà tá a dáṣọ tá
ò rílẹ̀ fi wọ́.
Ajayi Folasade ìyá ẹni àádọ́ta ọdún tó n kàwé lọ́wọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ girama Ilorin Grammar School, IGS.
O jẹ iyalẹnu pe iya yii, gbe ọjọ ori ti si ẹgbẹ kan o si pinu lati maa ba awọn ẹgbẹ ọmọ-ọmọ rẹ jokoo pọ ni kilaasi tori pe
o fẹ tẹsiwaju imọ.
“Igba ti gbogbo igbiyanju mi lati kawe n bọ si pabo, mo lọ si ileewe ti ijọ kan to wa lẹgbẹ ile wa ni 2012 ti mo si maa n jokoo pẹlu awọn ọmọde to wa nibẹ”.
Folashade ni nigba ti oun tun gbọ ti awọn ajọ kan loun tun lọ darapọ mọ wọn ti oun si gba iwe ẹri kika ileewe alakọbẹrẹ ja.
Iroyin sọ pe o lọ forukọ silẹ lati darapọ mọ kilaasi onipele ikeji, Jss 2 tori o wu u lati kawe ki oun naa si di olukọni lọjọ kan.
O wu u lati jẹ moriya fun awọn agbalagba to jẹ ẹgbẹ tirẹ naa lati ma jẹ ki ala wọn wọmi lai fi ti ọjọ ori wọn ṣe.
Nibayii, ileeṣẹ eto ẹkọ ni ipinlẹ Kwarra gan ti ni iwuri ni igbesẹ arabinrin naa jẹ ni ọjọ ori rẹ.
Olukọ kilaasi “Anti Ṣade” gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe e sọ pe o ya awọn lẹnu pe o n ṣe deedee ni kilaasi.
Ọmọdekunrin to tun jẹ Balogun kilaasi anti Ṣade sọ pe iru wọn lawọn n fẹ ni ileewe tori awọn fẹran wọn bi wọn ṣe n jafafa ninu kilaasi.