Ìjọba Cross River gba iṣẹ́ lọ́wọ́ adarí ilé ẹ̀kọ́ méjìlá lórí ẹ̀sùn rìbá

Ìjọba Cross River gba iṣẹ́ lọ́wọ́ adarí ilé ẹ̀kọ́ méjìlá lórí ẹ̀sùn rìbá

Ọrẹ Òtítọ́jù

Adarí ilé ẹ̀kọ́ girama méjìlá ti gba ìwé ẹ lọ ọ́ gbélé yín ní ìpínlẹ̀ Cross River, nígbà tí wọ́n gbé àwọn kan láti ilé ẹ̀kọ́ kan lọ sí òmíràn.

Eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin bi ijọba ipinlẹ ọhun ṣe fẹsun riba kan awọn adari ile ẹkọ naa.

Kọmiṣọnna eto ẹkọ ipinlẹ ọhun, Ọjọgbọn Godwin Amanke lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan niluu Calabar.

O ni “A ti fun ọpọ adari ile ẹkọ ni iwe lati wa ṣalaye tẹnu wọn,

a ti gba iṣẹ lọwọ adari ile ẹkọ mejila, a ni ki mẹfa lọ rọkun nile nigba ti a gbe awọn mẹrindilogun lati ile ẹkọ kan lọ si omiran.”

O ni oun gbọ pe awọn adari ile ẹkọ n san owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ki wọn le gbe wọn lati ile ẹkọ ti wọn n fẹ.

Amanke sọ siwaju si pe ijọba mọ nipa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ile ẹkọ girama, awọn si ti bẹrẹ isẹ lori rẹ.

Nigba to n sọrọ lori awọn aṣeyọri rẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna, Amanke sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣatunṣe awọn ile ẹkọ ti ogiri rẹ ti n wo.

O ni “To ba ṣeeṣe fun mi, mo maa fun awọn araalu ni ẹkọ ọfẹ, mo ṣe bẹẹ ri gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ.”

O pari ọrọ rẹ pe nnkan bii ẹgbẹrun kan olukọ tuntun ni ijọba naa n gba siṣẹ kaakiri ipinlẹ ọhun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here