Àwọn òṣìṣẹ́ báńkì tó gbówó ńlá jáde lásùnwọ̀n oníbàárà ti rẹ́wọ̀n he
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ikún ń jọ̀gẹ̀dẹ̀,ikún ń rẹ́dìí,ikún ò tètè mọ̀ pé n tó dùn ń pani.
Àwọn òṣìṣẹ́ báńkì méjì kan, Agbo John Agama àti Edoh Steve, ni wọ́n ti dèrò ẹ̀wọ̀n báyìí látàrí àwọn ẹ̀sù-un jìbìtì, ìlẹ̀dí àpò pọ̀ lórí owó tó tó bíi mílílọ̀nù mẹ́sàan-án Náírà àti ààbọ̀ (9.4 million).
Onidaajọ Mojisọla Ọlajuwọn ti ile-ẹjọ giga ilẹ wa to wa niluu Abuja, lo dajọ awọn ọdaran naa ‘l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023.
Ẹsun oniga kan ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa, EFCC, ẹkun Makurdi, nipinlẹ Benue, fi kan wọn ni wọn fi ṣedajọ awọn ọdaran mejeeji ọhun.
Gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan wọn, awọn ọdaran mejeeji yii pẹlu awọn agbodegba wọn ti wọn ti fẹsẹ fẹ ẹ, ni wọn sọ pe lasiko ti wọn ṣi jẹ oṣiṣẹ nile ifowopamọ Access Bank, ẹka ti Makurdi, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Benue, ni wọn lo irinṣẹ imọ ẹrọ kan ti wọn ko lẹtọọ si lati gba obitibiti owo ninu apo banki ọkunrin kan to n jẹ Mejuru Chibueze Gospel ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2021.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn yii ni wọn lo ta ko abala ikẹtalelọgbọn iwe ofin to sọrọ lori iwa jibiti ori ẹrọ ayelujara ti ọdun 2015, ti ijiya si wa fun un labẹ abala ofin ọhun bakan naa.
Ṣugbọn awọn mejeeji ni awọn ko jẹbi.
Onidaajọ Ọlajuwọn waa paṣẹ pe ki ẹni kọọkan wọn lọọ faṣọ penpe roko ọba fun ọdun mẹta mẹta. Bẹẹ naa ni wọn tun pa ẹni kọọkan wọn laṣẹ lati san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100, 000) owo itanran fun ijọba apapọ, ki kaluku wọn si da miliọnu meji Naira o le ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (2.1 million), pada fun ọkunrin ti wọn lu ni jibiti owo.