Hèèmọ̀! Abilékọ kan já bọ́ lẹ́yìn ọ̀kadà, ò sì gbabẹ̀ dèrò ọ̀run

Hèèmọ̀! Abilékọ kan já bọ́ lẹ́yìn ọ̀kadà, ò sì gbabẹ̀ dèrò ọ̀run

Ọrẹ Òtiọ́jù

Ìṣẹ̀lẹ̀ à-gbọ́-bomi-lójú ló ṣẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún yìí, níbi tí abilékọ kan ti dágbére fáyé. Ọkọ rẹ̀ ló fi ọ̀kadà Bajaj, tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ TTN 08 VG, gbé e, tó sì jókòó sẹ́yìn ọkùnrin náà pẹ̀lú ọmọ wọn, lásìkò tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀sì ládùúgbò Fajol, agbègbè Ọ̀báńtokò, nílùú Abẹ́òkúta.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣalaye pe iṣẹlẹ buburu yii waye lasiko ti ọkọ oloogbe fẹẹ sare pẹwọ fun ọkada to fẹẹ kọ lu wọn lati iwaju. Ọkada to n bọ niwaju, to si jọ pe o fẹẹ rọ lu wọn lọkunrin naa fi sare pẹwọ, ti iyawo ẹ to jokoo sẹyin si ja bọ latari ẹru biba ati bi ko ṣe jokoo daadaa tẹlẹtẹlẹ, oju-ẹsẹ to ṣubu naa lo dagbere faye. Ṣugbọn ohun to ba ni lọkan jẹ ni pe ọkada keji to fẹẹ rọ lu tọkọ-taya naa ko duro ṣugbaa wọn, niṣe lo sa lọ”.

Agbẹnusọ ajọ to n ri si igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, Ogun Traffic Compliance and Enforcement Corps (TRACE), Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe iwakuwa ẹni to wa ọkada lo jẹ ki ọwọ ẹ tase, to fi tibẹ sọ ijanu rẹ nu, eyi to pada ṣokunfa bi obinrin naa ṣe ṣubu, to tun fori gbalẹ nibi to ja bọ si, to si gbabẹ ku lojiji.

O tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa ti wọ ọkada naa kuro loju titi fun iwadii to peye, awọn mọlẹbi oloogbe si ti gbe oku ẹ kuro nibẹ.

Nigba to n ranṣẹ ibanikẹdun sawọn mọlẹbi oloogbe, Akinbiyi gba awọn ọlọkada nimọran lati maa ṣe suuru, ki wọn si maa ṣọra pẹlu ere asapajude lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here