Ọlọ́pàá mú tọkọtaya tó ń lu ọmọ wọn ní ìlù ẹranko ní Èkó

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọlọ́pàá mú tọkọtaya tó ń lu ọmọ wọn ní ìlù ẹranko ní Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti mú obìnrin kan àti olólùfẹ́ rẹ̀, fún ẹ̀sùn pé wọ́n fi ìyà jẹ ọmọdé méjì, ní agbègbè Egbeda ní ìpínlẹ̀ náà.

Obìnrin náà, Busola Oyediran, tó jẹ́ ìyà àwọn ọmọ náà, àti ọkọ rẹ̀ tuntun, Akebiara Emmanuel, ni ọwọ́ tẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà jẹ́ ọdún márùn-ún àti ọdún méjì.

Ìròyìn sọ pé àwọn alajọ́gbelé tọkọtaya náà, tó rí bí wọ́n ṣe máà ń lu àwọn ọmọ ọ̀hún, èyí tó ti dá oríṣìíiríṣì ọgbẹ́ sí wọn lára, ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá l’étí.

Èyí sì ló mú kí ọlọ́pàá fi òfin gbé wọn lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kínní, 2023.
Àjọ tó ń gbógun ti fífi èèyàn ṣe òwò ẹrú àti ìlòlulò ẹ̀dá, NAPTIP, sọ lójú òpó Twitter rẹ̀ pé tọkọtaya ọ̀hún ti wà nì àtìmọ́lé.

Bákan náà ní àjọ náà sọ pé wọ́n ó gbé àwọn méjèèjì lọ sílè ẹjọ́, lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kínní, 2023.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here