Àjọ “INEC” fi kún ọjọ́ gbígba káàdì ìdìbò

Àjọ “INEC” fi kún ọjọ́ gbígba káàdì ìdìbò

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ yìí INEC ti kéde àfikún ọjọ́ sí ọjọ́ tí àwọn aráàlú ní ànfàní láti gba káàdì ìdìbò fún ètò ìdìbò ọdún 2023.

Saaju ni ajọ ọhun ti kede pe awọn yoo fi opin si igba kaadi idibo lọjọ kejilelogun ọsu kinni ódun yii ṣugbọn wọn ti sọ di ọjọ kọkandilọgbọn oṣu kinni ọdun ta a wa yii.

Ikede yii waye lẹyin ipade ti ajọ naa ṣe Lọjọbọ ọsẹ yii.

Ninu atẹjade ti kọmisọna ajọ INEC, Festus Okoye fi ransẹ si awọn akọroyin,
o ni “Ajọ INEC ti pinnu lati jẹ ki awọn oludibo to fi orukọ silẹ gba kaadi idibo wọn saaju eto idbo. Fun idi eyi, ati fi ọjọ mẹjọ kun ọjọ to yẹ ki gbigba kaadi idibo wa sopin.

“O yẹ ki gbigba kaadi idibo wa sopin lọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun, sugbọn a ti fi ọsẹ kan kun un, ti yoo si wa sopin lọjọ kọkandinlọgbọn .

“Asiko ti awọn eeyan le gba kaadi idibo wọn,wa laarin ago mẹsan an arọ di ago mẹta ọsan. A n sisẹ ni ipari ọsẹ ati ọjọ isinmi pẹlu.”

Aipẹ yii ni ajọ INEC kede pe mimi kan ko ni mi awọn lati sun eto idibo siwaju.

Alaga Ajọ naa, Mahmood Yakubu ni gbogbo eto lo ti wa nilẹ eyi ti yoo mu eto idibo lọ lai si rogbodiyan rara.

Yakubu ni ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọ fi ọkan wọn balẹ lori ọrọ eto idibo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here