Ayo abara tintin, oserebinrin, Mo Bimpe,  kede pe oun ati oko re, Lateef Adedimeji n reti ibeji.

Ayo abara tintin, oserebinrin, Mo Bimpe,  kede pe oun ati oko re, Lateef Adedimeji n reti ibeji.
Mo Bimpe ati Adedimji

Mary Fagbohun

Oserebinrin Mo Bimpe ti kede pe oun ati oko re ati akegbe re, Lateef Adedimeji, n reti ibeji.

O fi irohin ayo naa lede ninu ateranse ajodun odun kan ti igbeyawo won pe laipe yii, Mo Bimpe pe Lateef ni “Baba ibeji”, ti o si gbadura pe ni odun ti o n bo won yoo se ajodun naa pelu awon ibeji won.

“Ku oriire ajodun igbeyawo wa akoko eni temi, baba awon omo ti a o tii bi, Baba ibeji 🤩

” Ni iwoyi odun to n bo, a o se ajoyo yii pelu awon omo wa” ni o ko.

Ateranse Mo Bimpe fun ajodun igbeyawo si oko re lekunrere

“Ni odun kan seyin, mo so BEENI si titi lae fun okunrin ti o wuni lori yii.

“Oko mi owon @adedimejilateef

Ojo ti o dara ju ni igbesi aye mi ni ojo ti mo di iyawo re, ojo ikeji ni ojo ti mo pada re ati ojo keta ni ojo ti mo so BEENI lati fe o.

“Mo dupe lowo Olorun pe mo ni o ninu aye mi.

“Mo ri ara mi bi oloriire ati eni ti a bukun bi mo se re eni bi okan mi ati ore timotrimo ninu oko mi. O ti fihan mi ohun ti ife je ni tooto, iwo ni idi ti inu mi fi n dun ni gbogbo ojo, o si je olutunu mi ni ojo ibanuje, o n kimi fun aseyori o si n gbami niyanju lati mase kuna.

Inu mi dun pe mo je iyawo re.

O seun fun wi pe o n mu ki alafia tesiwaju ninu igbeyawo wa, mo ti ni odun ti o dara ni alafia pelu re ife mi

O se fun awon iranti ayo ti o fun mi ati fun odun to n bo wa, mi o le duro lati ni iriri ti o dara pelu re si.

“Ku oriire ajodun igbeyawo wa akoko eni temi, baba awon omo ti a o tii bi, Baba ibeji 🤩

” Ni iwoyi odun to n bo, a o se ajodun yii pelu awon omo wa. Mo nife re pupo okomi.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here