Ilé isé̩ ìdárayá kò rí àtìle̩yìn kankan láti ò̩dò̩ Ìjo̩ba – Emmanuel Ayilo̩la

  • Ilé isé̩ ìdárayá kò rí àtìle̩yìn kankan láti ò̩dò̩ Ìjo̩ba – Emmanuel Ayilo̩la

    Mary Fágbohùn

    Olugbere jade Naijiria kan, Emmanuel Ayilola, ti ke pe ijoba lati se iranlowo ati pe ki won fi aaye gba ile ise idaraya lati goke ni orile ede yii, o wi pe ile ise naa le e fi opin si oro ainise laarin awon odo ati pe yoo si mu owo goboi wole fun ijoba Naijiria.

    Ayilola, eni to sapejuwe ile ise idaraya bii eyi ti o won sowo to si ni ere lori, figbe ta pe ijoba ko se nnkankan lati ran ile ise naa ati awon osere tiata lowo.

    O soro pelu awon oniroyin ni Akure, oluilu ipinle Ondo, lori ibi ti ile ise idaraya de duro ni Naijiria.

    O wi pe, “Ile ise idaraya je eka ti o lere. Awon omo Naijiria n pa owo wole lati ibe ni orisiirisii ona. Sugbon o se ni laaanu pe ijoba ko se idokowo si ile ise yii rara. Ijoba n se die tabi ka so pe ko si nnkankan ti won n se lati ti ile ise yii leyin. Lati ya fiimu won sowo. Lati se agbega ebun abinibi gan an o gba opolopo isinmi le owo.

    “Ile ise igbasile fiimu meloo lo je ti ijoba? Se awon eniyan n ri owo ya lati odo ijoba? Ko si ile ifowopamo kan to fe ya eka yii lowo. Atileyin wo ni awon eniyan to wa ni eka yii n ri lati odo ijoba? Mo mo iye owo ti mo na lati da ile ise igbasile fiimu sile. O gba oore ofe Olorun lati se aseyori. A o ti debe sugbon sibe a dupe lowo Olorun wi pe ibi kan lati bere.”

    Olugbere jade naa, eni ti o tun je agbejoro, wi pe inilo wa fun idanisile eka ti yoo ma a ri si oro idaraya lati le e dojuko gbogbo isoro ti eka naa n koju.

    “Ijoba wa ni lati gbaruku ti ile ise yii. Won gbodo fi aaye gba awon ti o wa ni eka yii lati se aseyori. A ti pe lati ni iwe ti o faye gba won lati sise naa ko rorun.

    “Idi niyi ti mo fi ro pe eka ijoba kan gbodo wa ti yoo ma a ri si ohun ti o n lo ni ile ise idaraya, eleyii ko buru rara. Opolopo nnkan ni yoo niyanju ti won ba se eyi. Yoo je ise kan gbogi fun eka ijoba yii lati sise lori gbogbo ohun to niise pelu oro idaraya. Awon ajo to ti wa tele yoo ma sise labe eka ijoba yii. Eleyi se e se nitori pe ile ise naa tobi,” ni ohun ti o fikun n.

    Ayilola tun beere fun ofin ti yoo de isowo idaraya lati odo awon asofin ki won le e se igbelaruge ati ki won le e dabo bo ile ise naa, o wi pe afarape je isoro kan gbogi ti ile ise naa n dojuko ati pe won nilo atileyin ijoba lati koju isoro naa.

    “E gba pelumi pe ile ise idaraya je okan lara ile ise to n dagba si i lojoojumo ni Naijiria. Ni pato, Nollywood Naijiria wa lara awon ile ise fiimu to tobi ju to si n da gba si i lojoojumo ni Naijiria. Eka orin ko gbeyin ninu ile ise idaraya. E e ri pe orin ile okeere ko lese nle mo ni Naijiria. Ipa ti ofin n ko ko se e fowo ro seyin. Mo ti n wo ofin to dara lati fi se igbelaruge ati idabo bo ile ise idaraya ni Naijiria ki o le e se fiyanga lagbaye.

    “Ko dami loju pe a ri ofin to to lori ile ise idaraya. Ile ise idaraya tobi o si ni ere. Opo eniyan lo ti laluyo lorisirisi eka ni ile ise naa. Abadofin fun idasile eka ijoba pataki lati le e dari ile ise idaraya ni Naijiria kii se aseju. Isoro kan gbogi ni ile ise naa ni afarape. Mo ro pe gbogbo wa gbodo sise papo lati dojuko eyi pelu irinse ofin,” ni ohun ti olugbere jade naa toka si.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here