Ikú dóró, Adé̩rìnín-pòsónú, Isbae U, pàdánù bàbá re̩ Kamal Adebayo.
Mary Fágbohùn
Ogbontarigi osere tiata Yoruba, Kamal Adebayo, ti gbogbo eniyan mo si Sir Kay ti je Olorun nipe.
Oloogbe naa ni baba aderinposonu, Abidemi Adebayo, ti gbogbo eniyan mo si Isbae U.
Alaga ibudoko ipinle Eko, Musiliu Akinsanya, ti gbogbo eniyan mo si MC Oluomo, ti kede iku osere tiata naa ni ojo Isegun ni oju opo Instagram re.
MC Oluomo ko o pe, “Pelu okan wuwo ni mo fi kede ipapoda Alhaji Kamal Adebayo (Sir Kay). Ki Olorun te si afefe ire. Sun re Sir Kay.”
Leyin ikede naa, awon osere tiata lokunrin ati lobinrin ti kedun oloogbe naa ni oju opo Instagram won.
Pelu abela onina lori, Faithia Williams, ko o pe, “Bi aye se ri re. Olorun… Sir Kay”, pelu afihan ekun sisun.
Yomi Fabiyi fi aworan oloogbe naa lede, pelu akole, ” O di gba kan naa, Ajagun Sir K. Wabili Kabbar. Sun re agba okunrin. Mo rewesi.”
Amo sa, Isbae U, ko ti soro lori ipapoda baba re titi di akoko yii.
Aderinposonu naa ni o fun baba re ni ebun owo milionu kan naira ni osu kejo fun ojo ibi re.
Ohun ti o se okunfa iku Sir Kay ni a ko ti i mo.