Ìdí tí mo fi yarí pé n ò se òsèlú – Òsèré tíátà Nkem Owoh

Ìdí tí mo fi yarí pé n ò se òsèlú – Òsèré tíátà Nkem Owoh

Mary Fágbohùn

Ogbologbo osere tiata, Nkem Owoh, ti so pe pelu gbogbo akitiyan awon kan lati ro oun pe ki oun towobo oro oselu, ni oun ko jale nitori pe oun le e de oke tan, ni ibi ti eru ti n ba oun kii arun ti o n se eto oselu Naijiria ma ba a ran oun.

Owoh, eni ti o sapejuwe ara re gege bi eni ti eru kii ba ninu iforowero kan lori eto idanilara aarin ose, o wi pe oun deyinko oro oselu nitori pe o feran lati ma a mu ki inu awon eniyan dun pelu iru eni ti o je.

Nigba ti o woye eto idibo ti o n bo lona, osere tiata naa wi pe, “Ma kan lo dibo ni. Mo ti gbiyanju lati ma se kopa ninu oselu Naijiria lapapo bo tile je wi pe mo mo pe awon oloooto si wa ninu oselu, sugbon eto oselu naa je arun to buruku ju.

“Opo eniyan ti gbiyanju lati fa mi wo inu oselu sugbon mo mo pe bi mo ba ti ori boo, arun to wa nibe yoo ran mi, mi o si fe e. Nitori naa, mo gba bi mo se wa yii. Orileede yii yoo dara si i nigba ti a ba ni adari to dara ni gbogbo ona. Laipe yoo dee nitori mo ti n ri ami re.

“Orun mi ko le e gbe e (oselu). Onkan ni wi pe, mo feran ibi ti mo ti le rerin; e ri pe mo n rerin, eyin naa si n rerin. Atipe mo n danikan rin irinajo bi mi o se beru nnkankan. Bi mo ba wa ninu oselu, ma a ti de ibi ti eru yoo ti ma a bami, mi o fe beru rara.”

Owoh wi pe ile ise fiimu n jiya aini owo ati idanimo lati odo awon asofin, o fikun un pe afokansi yii yipada nitori awon asofin ti bere si ni da Nollywood ati awon osere tiata mo.

Osere apanilerin naa wi pe, “Ile ise fiimu, ati eka idanilaraya lapalo, e ko le e ri ija laarin won sugbon e lo si aarin oselu, e o ri ere.

“Lapapo, ni ile ise fiimu lonii, a ni idojuko owo ati idanimo lati odo awon asofin. Sugbon bayii, awon asofin ti mo wa nitori won ri pe a n mu ki owo wole si orileede yii. Awon asofin wa n wo ona yii gege bi orisun owo yato si epo robi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here