Inú mi kìí dùn tí wọ́n bá pè mí ní Jubril Sudan – Buhari

Inú mi kìí dùn tí wọ́n bá pè mí ní Jubril Sudan – Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ó ní súúná tí í bá oníkálùkù lára mu, Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ pé inú òun kìí dùn tí àwọn èèyàn bá ń pe òun ní Jubril láti Orílẹ̀ Sudan.

Ó ní àwọn tó ń pe òun lórúkọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú ojú òun kúrò lára iṣẹ́ tó yẹ kí òun ṣe fún ìlú ni.

àrẹ Buhari ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú fíìmù kan tí wọ́n ṣe nípa ìgbésí ayé e rẹ̀ èyí tí wọ́n pè ní “Celebrating a Patriot, a Leader, an Elder Statesman.”

Inú fíìmù ọ̀hún ló ti sọ̀rọ̀ náà àtàwọn ọ̀rọ̀ mí-ìn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀.

Ọdún 2018 ni ọ̀rọ̀ ìkéde ‘Jubril láti Sudan’ náà kọ́kọ́ ṣẹ́yọ nígbà tí Buhari padà dé sí Nàìjíríà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn tó lọ lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ láti tọ́jú àìsàn kan tó ń bá a fínra.

Bó ṣe dé báyìí làwọn kan ń sọ pé Ààrẹ ti kú, àti pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jubril, ọmọ orílẹ̀-èdè Sudan ni wọ́n gbé padà wá sí Nàìjíríà, tó sì ń ṣe bí i Ààrẹ lé wa lórí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Buhari ní ọ̀rọ̀ náà kò pa òun lẹ́rìn-ín rárá, àmọ́ àwọn tí wọn kò fẹ́ kí òun gbájúmọ́ iṣẹ́ ti wọ́n dìbò yan òun fún, ló ń gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ọ̀hún kiri.

O ní “Ohun tó ká mi lára ni bí mo ṣe má a ṣe àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn aráàlú.”

Ààrẹ Buhari tún ti sọ pé méjì lára àwọn ọmọ òun ló bá àìsàn ‘Sickle Cell’ lọ.

Buhari ló fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún léde lọ́jọ́ Ẹtì, níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rin ọdún rẹ̀, èyí tí àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún-un.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí ayé e rẹ̀, ó ní àwọn ọmọ òun méjì tí ìyàwó òun àkọ́kọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Safinatu bí fún òun kú nítorí àìsàn náà.

Ó ní ẹ̀yin tí òun pàdé Aisha Buhari ni òun lọ ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, kí irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ má baà wáyé mọ́.

Ọdún 1971 ni Buhari fẹ́ Safinatu, wọ́n sì bí ọmọ márùn ún fún ara wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here