Ikú tún ṣọṣẹ́ o! Aṣojú Orílẹ̀èdè Naijiria sí Spain, Ademola Seriki, jáde láyé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bíkú bá ti dé kò sóògùn mọ́.Aṣojú orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀èdè Spain, Ademola Seriki, jáde láyé. Àgbà olóṣèlú ọ̀hún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Èkó ló kú sí ìlú Madrid ni ẹni ọdún Mẹ́tàlélọ́gọ́ta.
Àwọn mọ̀lẹ́bí kéde ikú náà nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn ọmọ olóògbé fi síta fún àwọn akọ̀ròyìn ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ, wọ́n ní Bàbá náà jàde láyé nílùú Madrid.
Nínú àtẹ̀jáde náà; “Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, tí a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni a fi ń kéde ìpapòdà Bàbá, Ọkọ, Ẹ̀gbọ́n àti Ọ̀rẹ́ wa, Ambassador Demola Seriki, ẹni tó jáde láyé lọ́jọ́ Kẹẹ̀ẹ́dógún, ọsù kejìlá, ọdún 2022.
“Ó jáde láyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní àyíká àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní ìlú u Madrid, lórílẹ̀èdè Spain.”